Question 13
Sọ ìtumọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orúkọ wọ̀nyí:
(a) Olúgbódi
(b) Ìgè
(d) Kíyèsẹ́ní
(e) Ọkọ́ya
(ẹ) Òní
(f) Ọ̀kánlàwọ́n
(g) Ìlọ̀rí
(gb) Ọ̀kẹ́
(h) Ẹ̀ta-òkò
(i) Dàda
Observation
Candidates were required to state the meaning of each of the Yoruba traditional names listed above.
Ìtumọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orúkọ:
(a) Olúgbódi: ọmọ tí ó ní ìka ọwọ́/ẹ̀sẹ̀ mẹ́fà.
(b) Ìgè: ọmọ tí ó mú ẹsẹ̀ dípò orí wá sí ayé ní ìgbà tí a bí i.
(d) Kíyèsẹ́ní: ọmọ tí ó kéré jọjọ/púpọ̀ nígbà tí a bí i tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tẹ́ ẹ sórí ẹní, ènìyàn lè má tètè mọ̀ pé ó wà níbẹ̀.
(e) Ọkọ́ya: àbíkú ọmọ ni èyí tí à ń kìlọ̀ fún pé tí ó bá tún kú, kò sí ọkọ́ kankan láti gbẹ́ ilẹ̀ tíwọ́nmáasin ín símọ́ àti pé gbogbo ọkọ́ tí ó yẹ láti gbẹ́ ilẹ̀ náàni ó ti ya.
(ẹ) Òní: ọmọ tí ó ń ké tọ̀sán tòru lẹ́yìn ìgbà tí a bí i.
(f) Ọ̀kánlàwọ́n: ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí òbí rẹ̀ bí lé àwọn ìyókù tí wọ́n jẹ́ obìnrin.
(g) Ìlọ̀rí: ọmọ tí ìyá lóyún rẹ̀ láìṣe nǹkan oṣù.
(gb) Ọ̀kẹ́: ọmọ tí ó wà nínú àpò-ìbírẹ̀ nígbà tí a bí i.
(h) Ẹ̀ta-òkò: ọmọtí a bíṣeìkẹtanínúàwọnìbẹta.
(i) Dàda: ọmọ tí irun orírẹ̀ ta kókó láti ọ̀run wá.
Some of the candidates who attempted this question did justice to it.