Question 5
Fi àpẹẹrẹ mẹ́ta mẹ́ta ṣàlàyé ọ̀kọ̀ọ̀kan àtúnpín ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ wọ̀nyí:
(a) ọ̀rọ̀-orúkọ aṣèbéèrè
(b) ọ̀rọ̀-orúkọ ibìkan
(d) ọ̀rọ̀-orúkọ ìgbà
(iv) ọ̀rọ̀-orúkọ òǹkà
(v) ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà
Observation
Candidates were required to explain and give three examples of each of the sub classification of nouns.
Àlàyé àtúnpín-ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-orúkọ pẹ̀lú àpẹẹrẹ
Àtúnpín-ìsọ̀rí Ọ̀rọ̀-orúkọ |
Àlàyé |
Àpẹẹrẹ |
a) Ọ̀rọ̀-orúkọ aṣèbéèrè |
Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí a fi máa ń ṣe ìbéèrè/ó máa ń rọ́pò ọ̀rọ̀-orúkọ mìíràn nínú gbólóhùn ìbéèrè |
Kí, Ta, Èwo, Èló, Ibo, Elélòó, abbl. |
b) Ọ̀rọ̀-orúkọ ibìkan |
Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ ti a lè fi ‘ibo’ ṣe ìbéèrèfún |
Ìbàdàn, Èkó, Ìlọrin, ọjà, Ifẹ̀, ìta abbl. |
d) Ọ̀rọ̀-orúkọ ìgbà |
Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó máa ń tọ́ka sí àkókò àti ìgbà kan pàtó |
ọ̀sán, alẹ́, òní, ọ̀la, oṣù, ọdún, ìjẹrin, òwúrọ̀, ìrọ̀lẹ́, òru, abbl. |
e) Ọ̀rọ̀-orúkọ òǹkà |
Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí a máa ń ṣẹ̀dá òǹkà lára rẹ̀ |
Ení, Èjì, Ẹ̀ta, Ẹ̀rin, Àrún, Ẹ̀fà, Èje, abbl. |
ẹ) Ọ̀rọ̀-orúkọ aṣeékà |
Èyí ni ọ̀rọ̀-orúkọ tí ó tọ́ka sí nǹkan tí a lè kà |
Ilé, Ẹ̀wù, Ìwé, Ọmọ, Ajá, abbl. |
Only a few of the candidates who tackled this question were able to explain and give examples of each of the subclassification of nouns