Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2022

Question 9


Sọ̀rọ̀ lórí Àyànná gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ìtàn

Observation

 

Candidates were required to describe Àyànná, one of the characters, in the prose.
Àyànná gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá-ìtàn:

  1. Àyànná jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọlọ́mọge Òkèrèwè.
  2. Òun àti Mọrèmi pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ni wọ́n jọ wà ní ọjà Ìtakọgun.
  3. Òun ni àbíkẹ́yìn bàbá rẹ̀.
  4. Ìyá rẹ̀ ni ìyàwó karùn-ún tí bàbá rẹ̀ fẹ́.
  5. Òun nìkan ni ọmọ tí ìyá rẹ̀ bí fún bàbá rẹ̀.
  6. Ṣàdédé ni wọ́n ránṣẹ́ pè é pé bàbá rẹ̀ kú.
  7. Àyànnà bara jẹ́ púpọ̀ lórí ikú bàbá rẹ̀.
  8. Inú rẹ̀ kò dùn sí ipò tí ó bá ìyá rẹ̀ ní ilé.
  9. Àyànná kópa nínú orò ìsìnkú tí wọ́n ṣe fún bàbá rẹ̀.
  10. Àyànná kò rí ohun tí ó burú nínú orò ìsìnkú tí wọ́n ṣe fún bàbá rẹ̀.
  11. Àyànná fara mọ́ àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Ifẹ̀ ní tirẹ̀.
  12. Ẹnú ya Àyànná púpọ̀ nígbà tí Mọrèmi rí orò ìsìnkú bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìjẹgàba akọ lórí abo.
  13. Àyànná kò fara mọ́ àwọn àléébù tí Mọrèmi kà sílẹ̀ níbi ìsìnkú bàbá rẹ̀

Candidates’ performance in this question was poor.