Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2022

Question 6

Nínú ìtàn “Ìjàpá kó gbogbo ọgbọ́n ayé sínú kèǹgbè”, ṣàlàyé ohun tí Ìjàpá rò kí ó tóó kó gbogbo ọgbọ́n ayé sínú kèǹgbè.

Observation

Candidates were required to give reasonswhy Ìjàpá, a character, in the folktale decided to hoard all the wisdom in the world in a gourd in the folktale “Ìjàpá kó gbogbo ọgbọ́n ayé sínú kèǹgbè”.

Ohun tì Ìjàpá rò kí ó tóó kó gbogbo ọgbọ́n ayé sínú kèǹgbè:

(i)      ó fẹ́ kí gbogbo ayé máa bọ̀wọ̀ fún òun
(ii)      ó fẹ́ẹ́ di alákòóso gbogbo ọgbọ́n ayé/ó fẹ́ẹ́ di ẹni tí ó lọ́gbọ́n jù lọ ní ayé
(iii)     ó fẹ́ẹ́ máa fi ọgbọ́n tọrẹ fún ẹni tí ó bá wù ú
(iv)     ó fẹ́ẹ́ máa ta ọgbọ́n fún ẹni tí ó bá nílò rẹ̀
(v)      ó fẹ́ẹ́ ti ipa títa ọgbọ́n di olówó rẹpẹtẹ
(vi)     ó fẹ́ẹ́ di olókìkí láàrin ìlú
(vii)    ó fẹ́ẹ́ di olùdámọ̀ràn fún àwọn aláṣẹ ìlú (ọba àti ìjòyè)
(viii)   ó fẹ́ẹ́ di alábàárò fún àwọn lóókọlóókọ

Candidates’ performance was commended by the chief examiner.