Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2022

Question 3


Ṣeàlàyéọ̀kọ̀ọ̀kanàwọnẹ̀yà-ara ifọ̀ wọ̀nyí:
(a)      ẹ̀dọ̀-fóró
(b)     ẹ̀ka kòmóòkun
(d)     gogóńgò
(e)      ahọ́n
(ẹ)      àfàsé

Observation

 

Candidates were required to describe each of the organs of speech above.

Àlàyé àwọn ẹ̀yà-ara ìfọ̀

(a)      Ẹ̀dọ̀-fóró: Oun ni orísun èémí gbogbo ìró èdè Yorùbá àyàfi ìró [kp] àti [gb] tí orísun èémí wọn jẹ́ àpapọ̀ èémí ẹ̀dọ̀-fóró àti ti ẹnu.

(b)     Ẹ̀ka kòmóòkun: Méjì ni ẹ̀ka kòmóòkun. Inú wọn ni èémí ẹ̀dọ̀-fóró máa ń gbà wọ inú kòmóòkun nígbà tí a bá ń pe ìró.

(d)     Gògòńgò: Ọ̀fun ènìyàn ni gògòńgò wà. Orí kòmóòkun ni ó dúró lé. Inú rẹ̀ ni tán-án-ná wà. Inú tán-án-ná ni àtúnṣe àti ìyípadà àkọ́kọ́ ti máa ń bá èémí. Ipò rẹ̀ ni ó máa ń jẹ́ kí ìró jẹ́ akùnyùn tàbí àìkùnyùn.

(e)      Ahọ́n: Ọ̀nà mẹ́ta ni a pín ahọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà-ara ìfọ̀ sí: iwájú, àárín àti ẹ̀yìn. Ahọ́n ṣeé gbé sí oríṣi ipò mẹ́rin: òkè/àhánupè, ẹ̀bákè/àhánudíẹ̀pè, ẹ̀bádò/àyanudíẹ̀pè, odò/àyanupè.

(ẹ)      Ètè: Méjì ni ètè: ti ìsàlẹ̀ àti ti òkè. Àwọn méjèèjì ṣeé gbé sí ipò láti lè fi gbé ìró jáde. Ètè lè ṣù roboto; ó sì lè tẹ́ pẹrẹsẹ, fún pípe àwọn ìró fáwẹ́lì.

(f)      Àfàsé: Ipò méjì ni àfàsé lè wà:ó lè gbé sókè kí ó dí ọ̀nà tó lọ sí imú; ó sì lè wá sílẹ̀ kí ó má ṣedí ọ̀nà tí ó lọ sí imú bí a bá ń pe àwọn ìró. Ipò rẹ̀ ni ó máa ń jẹ́ kí ìró jẹ́ àránmúpè tàbí àìránmúpè.