Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2023

Question 10

Báwo ni akéwì ṣe sọ pé ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì ṣe lè rí lára àwọn ènìyàn nínú ewì “Ọ̀rọ̀ Ẹnu Akéwì”?

Observation

Candidates were tasked to describe the effects of the poetic language on the listeners as evident in the poem.

akéwì ṣe sọ pé ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì ṣe lè rí lára àwọn ènìyàn:

  1. ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì lè dàbí ọrẹ́ tí máa ń na ni líle líle
  2. ìgbà mìíràn, á dàbí afẹ́fẹ́ àrọ̀dá òjò tí ó máa ń tu ni lára
  3. ìgbà mìíràn á dùn mọ́ni létí bí kí akéwì má dákẹ́
  4. ìgbà mìíràn, á kan gógó léti ẹni tí kò níí wùùyàn gbọ́
  5. ìgbà mìíràn á dùn bí oyin
  6. ìgbà mìíràn, á gúnni létí bí ìṣó
  7. ìgbà mìíràn akéwì á dàbí adájọ́; adájọ́ òdodo
  8. Ìgbà mìíràn, ọ̀rs ẹnu akéwì á dàbí àdììtú
  9. ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì dàbí ìlù gángan tí ó ń kọjú sí ẹnìkan tí sì ń kọ̀yìn sí ẹlòmín-ìn
  10. ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì kò ní ìtìjú èèyàn, á ranjú kankan bíi kọ̀ǹkọ̀ àtẹ̀mẹ́rẹ̀
  11. ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì rí kọ̀ǹbọ̀ bí òwú bọ́ lu ni
  12. ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì dà bí àlàyé tí ó máa ń la nǹkan yé ni nígbà mìíràn
  13. ìgbà mìíràn, ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì á dà bí ìtàn
  14. ìgbà mìíràn ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì á dà bí àlá níbi tí ìgbà gbé ń ka oníkà
  15. ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì jẹ́ ọ̀rs burúkú tí ó ń ṣiṣẹ́ rere
  16. ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì a fara hàn bí ìkìlọ̀
  17. Bí ewúro ni ọ̀rọ̀ ẹnu akéwì nígbà mìíràn, bí ó korò níbẹ̀rẹ̀, adùn á sì gbẹ̀yin rẹ̀

Candidates’ performance on this question was commendable.