Question 7
Nínú Oríkì Ìran Onígbòórí”, rọ́ ìtàn bí ìyá Mọ̀sè ṣe di ọlọ́mọ.
Observation
Candidates were required to narrate the story of how ìyá Mọ̀sè became a mother as evident in the oral poetry.
Bí Ìyá Mọ̀sè ṣe di ọlọ́mọ:
- Ìyá Mọ̀sè ló tẹ Ìgbórí dó
- Àgàn ni ìyá Mọ̀sè
- Ìyá yìí ti dàgbà/dògbó/léwú lórí
- Ó máa ń sunkún àìrọ́mọbí
- Ó ń fi ọwọ́ osùn tútù nu ògiri gbígbẹ/kò rí oyún ní/ó ń ṣe nǹkan oṣù láà lóyún
- Ó ń ṣọ̀fọ̀ ara rẹ̀ láìkú
- Amúṣàn-án yọjú nínú odò Asà
- Amúṣàn-án wá bú ọpa ó ní ìyá Mọ̀sè yóò finú ṣoyún, yóò sì fẹ̀yìn gbọ́mọ pọ̀n/ó ní ìyá Mọ́sè yóò bímọ ti ara rẹ̀
- Ìyá Mọ̀sè sì bí Ẹ̀gùn Ànùmí
- Báyìí ni ìyá Mọ́sè ṣe di ọlọ́mọ
Most candidates who attempted this question showed a lack of knowledge of the prescribed text: Babalọlá’s Àwọn Oríkì Orílẹ̀ Mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.