Question 5
Kọ àpẹẹrẹ kan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àtúnpín ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-ìṣe wọ̀nyí kí o si lo àpẹẹrẹ náà ní gbólóhùn.
(a) ọ̀rọ̀-ìṣe aṣàpèjúwe
(b) ọ̀rọ̀-ìṣe àkànmórúkọ
(d) ọ̀rọ̀-ìṣe alápèpadà
(e) ọ̀rọ̀-ìṣe aláìlẹ́ní
(ẹ) ọ̀rọ̀-ìṣe aṣokùnfà
(f) ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè
(g) ọ̀rọ̀-ìṣe apàṣẹ
(gb) ọ̀rọ̀-ìṣe aṣàpọ̀nlé
(h) ọ̀rọ̀-ìṣe asolùwàdàbọ̀
(i) ọ̀rọ̀-ìṣe agbẹ̀rún
Observation
Candidates were required to give one example each of the listed subclassification of verbs and use the examples in illustrative sentences.
Àpẹẹre fún Àtúnpín Ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-ìṣe àti ìlo wọn nínú gbólóhùn
S/N |
Àtúnpín ìsọ̀rí ọ̀rọ̀-ìṣe |
Àpẹẹrẹ rẹ̀ |
Gbólóhùn ìṣàpẹẹrẹ |
a |
ọ̀rọ̀-ìṣe aṣàpèjúwe |
ga, pọ́n, dúdú, dáa, pupa |
Ọsàn yìí ti pọ́n. |
b |
ọ̀rọ̀-ìṣe àkànmórúkọ |
pàdé, jókòó, gbàgbé, pẹ̀lé, retí, rántí |
Mo rántí ilé |
d |
ọ̀rọ̀-ìṣe alápèpadà |
ṣe..ṣe, rò..rò, kù...kù, mọ́...mọ́, fẹ́...fẹ́ |
Kọ́lá ni ó kù mí kù |
e |
ọ̀rọ̀-ìṣe aláìlẹ́ní |
dára, burú, dájú, dùn |
Ó dára kí a máa sọ òtítọ́. |
ẹ |
ọ̀rọ̀-ìṣe aṣòkùnfà |
mú, fi, da, kó ti |
Ó fi ilé dárà. |
f |
ọ̀rọ̀-ìṣe aṣèbéèrè |
dà, ńkọ́ |
Ìwé mi dà? |
g |
ọ̀rọ̀-ìṣe apàṣẹ |
Kú(níbi ìkíni), jọ̀wọ́, pẹ̀lẹ́, dákun |
Ẹ kú ìjókòó. |
gb |
ọ̀rọ̀-ìṣe aṣàpọ́nlé |
sáré, yára, rọra |
Wọ́n rọra yọ́ wa sílẹ̀. |
h |
ọ̀rọ̀-ìṣe asòlùwàdàbọ̀ |
bínú, tijú, jáyà, ṣíṣẹ̀ẹ́, bẹ̀rù, |
Inú bí mi. Mo bínú. |
i |
ọ̀rọ̀-ìṣe agbẹ̀rún |
jí (ni), gbá (ní), pa (ní), ṣe (ní), ta (ní), kó (ní) |
Adé gbá mi ní etí. |
Many candidates who attempted this question performed fairly well.