Question 4
a. Fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwọ̀nyí ní oríkì:
i. gbólóhùn oníbọ̀
ii. olórí awẹ́ gbólóhùn
iii. awẹ́ gbólóhùn afarahẹ
(b) Fa olórí awẹ́ gbólóhùn inú ọ̀kọ̀ọ̀kan gbólóhùn wọ̀nyí yọ
i. Ọ̀gá tí ó fẹ́ràn mi ti dé.
ii. Ó dá mí lójú pé Ọlọ́run ń bẹ.
iii. Gbogbo wọn ti lọ kí a tóó dé.
iv. Ìbáà lówó, kò lè jọba.
v. Bí mo bá lówó, màá kọ́lé.
vii. Ẹ jẹun kí ẹ tóó lọ.
Observation
Candidates were tasked to define a complex sentence in a(i), a main clause in a(ii), a surbordinate clause in a(iii) and identify the main clauses in the given sentences in b.
4. (a) Oríkì àwọn wúnrẹ̀n:
(i) Gbólóhùn Oníbọ̀: Èyí ni gbólóhùn tí a ti fi gbólóhùn kan há (ìhun) òmíràn.
(ii) Olórí awẹ́ gbólóhùn: Èyí ni apá kan tí ó lè dá dúró nínú gbólóhùn oníbọ̀
(iii) Awẹ́-gbólóhùn afarahẹ: Èyí ni apá kan tí kò lè dá dúró láìfi ara ti olórí awẹ́-gbólóhùn nínú gbólóhùn oníbọ̀
(b) Àfàyọ olórí awẹ́-gbólóhùn:
S/N |
GBÓLÓHÙN |
ÀFÀYỌ OLÓRÍ AWẸ́-GBÓLÓHÙN |
(i) |
Ọ̀gá tí ó fẹ́ràn mí ti dé |
Ọ̀gá ti dé |
(ii) |
Ó dá mi lójú pé Ọlọ́run ń bẹ |
Ó dá mi lójú |
(iii) |
Gbogbo wọn ti lọ kí a tóó dé |
Gbogbo wọn ti lọ |
(iv) |
Ìbáà lówó kò lè jọba |
Kò lè jọba |
(v) |
Bí mo bá lọwọ màá kọ́lé |
Màá kọ́lé |
(vi) |
Ẹ jẹun kí ẹ tóó lọ |
Ẹ jẹun |
Most candidates missed out on the definitions but perfomed well in the identification of the main clause.