Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2023

Question 12

Báwo ni a ṣe ń polówóọjà wọ̀nyí?
(a)      Ègbo
(b)     Ilá́
(d)    Ẹ̀kọ tútù
(e)      Àgbàdo sísè
(ẹ)      Ọsàn
(f)      Èkuru
(g)     Òrí
(gb)    Àmàlà
(h)     Ọṣẹ
(i)      Iṣu sísè

Observation

Candidates were required to state the mode of advertisement for each of the goods listed.

 

         


S/N

Ọjà

Ìpolówó Rẹ̀

a

Ègbo

Yọ́ọ̀rí ègbo, gẹ̀ẹ̀rẹ̀

b

Ilá

Òréré ilá o, ọbẹ̀ aàyò!
Ẹ filá jiyán o
Ilá olóje, àsèkúnkòkò

d

Ẹ̀kọ tútù

Oori bíike! Ẹ ẹ̀ jẹran ẹ̀kọ!
Ìrọmí ẹ̀kọ rè é o
Ẹ ò joori ire

e

Àgbàdo sísè

Erín o, ò pòróǹtò./ Láńgbé jinná o.
Ọ̀rọ̀kú orí ebè/ Ìbéèní àgbàdo, Láńgbá orí ebè./ Olóko ò gbowó/ Àpà ò béèrè

Ọsàn

Oyin ladùn ọsàn

f

Èkuru

Ẹ fèkuru jẹ̀kọ o./ ó fú/fún lójú ọ̀rẹ́ ẹ̀kọ o/ìbóǹbó èkuru o.

g

Òrí

Àsìkò òrí o./ Ẹ ẹ̀ ròrí èrò

gb

Àmàlà

Mo rò ó, ó yí bi àtè
Àròyì àmàlà

h

Ọṣẹ

Ọṣẹ mi àbùwẹ̀
Àhóòdá ọṣẹ o

i

Iṣu sísè

Mùyẹ́ o, ègbodò.
Iṣu epo mùyẹ́ ègbodò. Ẹ fiṣu lápo o
Èrú wà ń bẹ níbí. ‘o ń tú mùyẹ́ o. Ẹ rèrú gbígbóná, ẹ mu panu o.

Candidates’ performance in this question was commendable.