Question 8
Kí ni ó fàá tó fi jẹ́ pé òru nìkan ni Orò ń jáde?
Observation
Candidates were required to explain the origin of Orò’s nightly appearance as narrated in the text.
Ohun tí ó fà á tó fi jẹ́ pé òru nìkan ni Orò ń jáde:
(i) Òrìṣà ni Egúngún àti Oró ni ilẹ̀ Yorùbá
(ii) Ìtàn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìbejì ni àwọn méjèèjì
(iii) Orò lẹ̀gbọ́n, Egúngún làbúrò
(iv) Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn méjèèjì ń ṣe
(v) Ìyàwó wọn ni ó sì ń ta irè oko wọn lọ́dọọdún
(vi) Ìyàwó Egúngún ń fi owó díẹ̀díẹ̀ pamọ́, ó sì ń raṣọfún ọkọ rẹ̀
(vii) Onínà-án-kúnà-án obìnrin ni ìyàwó Orò, tìfun-lọ̀ràn ni, kì í rí owó fi pamọ́
(viii) Ìyàwó Orò kì í raṣọ fún ọkọ rẹ̀
(ix) Ní ọjọ́ kan, Egúngún àti Orò fẹ́ẹ́ lọ sí òde
(x) Egúngún kò sínú aṣọ tí ó jíire ṣùgbọ́n Orò kò rí aṣọ gidi kan wọ̀n
(xi) Èyí mú kí Orò rí àṣìṣe aya rẹ̀
(xii) Orò mú àtòrì rọ̀jọ̀rọ̀jọ̀, ó kó o bo ìyàwó rẹ̀
(xiii) Ìyàwó Orò sá, ó korí bọ igbó
(xiv) Orò lé e kò bá a nítorí pé ìhòhò ni Orò wà
(xv) Láti ìgbà náà ni Orò ti ń pe Ìyàwó yìí kágbó tí ó sì máa ń sọ pé ‘Bun-un-bun-un-bun-un’
(xvi) Egúngún a máa jáde láàárọ̀, lọ́sàn-án tàbí lálẹ́ nítorí aṣọ tí ó jíire ni ó máa ń wọ̀ sọ́rùn.
(xvii) Òru nìkan ni Orò fi ń rìn jáde nítorí ipò oníhòòhò tí ó máa ń wà
(xviii) Ìdí nìyí tí Orò fi máa ń jáde ní òru nìkan.
Candidates are required to mention the specific speech art of Ẹ̀gè Dídá.
The question was fairly tackled by those who read the text.