Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2018

Question 7

    Nínú oríkì Ìran Ológbì-ín, ṣàlàyé bí a ṣe mọ ẹni tí o ni eégún.


Observation

Candidates were required to narrate the tale of how the owner of the masquerade was identified in the lineage of Ológbì-ín.

Bí a ṣe mọ ẹni tó ni eégún nínú oríkì “Ìran Ológbìn-ín”:

  1. Àríyànjiyàn wáyé lórí ẹni tí ó ni eégún.
  2. Ọlọ́pọndà lóun ni òun ni eégún.
  3. Ẹ̀sà Ọ̀gbín lóun ni òun ni eégún.
  4. Ọlọ́jọwọ̀n náà lòun ni òun ni eègún.
  5. Aláràn-án náà ní òun lòun ni eégún.
  6. Èyí sì fa ìjà láàrin wọn.
  7. Wọ́n kó ara wọn lọ síwájú Aláàfin Ọ̀yọ́.
  8. Aláàfin Ọ̀yọ́ ní kí wọ́n ta kókó aṣọ.
  9. Kí wọ́n sì máa bọ̀ ní ààfin òun ní ọjọ́ keje.
  10. Gbogbo wọn ni wọ́n ta kókó aṣọ.
  11. Nígbà tó di ọjọ́ keje, wọ́n wá síwájú Abíọ́dún.
  12. Aláàfin ní kí gbogbo wọ́n jó, kí wọ́n ṣìju agọ̀ sílẹ̀.
  13. Bí Ọlọ́pọndà ṣe ṣíjú agọ̀ sílẹ̀, omi ni wọ́n bá nínú aṣọ.
  14. Wọ́n ni Ọlọ́pọ́ndà kọ́ ni ó ni eégún.
  15. Bí Aláràn-án ṣe ṣíjú agọ̀ sílẹ̀, igba abẹ́rẹ́ ni wọ́n bá létí aṣọ.
  16. Wọ́n ní Aláràn-án kọ́ ló ni eégún àti pé àrán ni ó lè rán.
  17. Bí Làgbàyí ọmọ ọ̀nà L’árè ṣe ṣíjú agọ̀ sílẹ̀, igi pẹlẹbẹ pẹlebẹ ni wọ́n bá létí aṣọ.
  18. Wọ́n ní igi lọmọ olórí ọlọ́nà ń gbẹ́.
  19. Bí Ẹ̀sà Ògbìn Ológbojò ṣe ṣị́jú agọ̀ sílẹ̀ gbugudu, igba eégún wẹẹrẹwẹ la bá nínú aṣọ.
  20. Wọ́n bá ni Ológbojò, òun gan-an lo ni eégún.
  21. Báyìí ni a ṣe mọ ẹni tí ó ni eégún.

Candidates’ performance was poor in this question. This suggests that candidates lack exposure to the selected text.