Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2018

Question 9

    Irú ẹ̀dá-ìtàn wo ni Ọ̀rẹ́-èwí jẹ́?


Observation

Candidates were expected to describe Ọ̀rẹ́-èwí, one of the characters in the novel Ìgbẹ̀yìn Laláyò Ń Ta.

Irú ènìyàn tí Ọ̀rẹ́-èwí jẹ́:

  1. Ọ̀rẹ́-èwí ni bàbá Òbíṣẹ̀san.
  2. Ìyàwó mẹ́ta ni ó ní
  3. Òbíṣẹ̀san ni àkọ́bí àti Dáódù rẹ̀.
  4. Iṣẹ́ sọ́yà/alapákó ni ó ń ṣe.
  5. Ó kó ẹbí mọ́ra, ó sì lọ́yàyà.
  6. Ó jẹ́ ẹni tó lawọ́, kì í ṣe ahun.
  7. Ó máa ń gba àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ràn rere.
  8. Ìlú Ìsẹ́yìn ni ó ń gbé bí ó tilẹ̀ jẹ́ ọmọ Ẹ̀fọ̀n ni.
  9. Ọdọọdún ló máa ń fi ọkọ̀ kó iṣu, èlùbọ́ àti ẹ̀ran-ìgbẹ́ lọ sí Ẹ̀fọ̀n láti pín fún àwọn ẹbí rẹ̀.
  10. Tọmọdé tàgbà, ẹbí àti ọ̀rẹ́ ni ó máa ń pín owó àti aṣọ fún.
  11. Olókìkí àti gbajúmọ̀ ni ní ìlú.
  12. Ọdún mẹ́ta gbáko ló fi wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn.
  13. Ìtọ́jú àìsàn tí ó ṣe é kó púpọ̀ nínú dúkìá àti owó rẹ̀ lọ, síbẹ̀ ó pàpà kú.
  14. Àwọn ohun ìní rẹ̀ tí ó kù lẹ́yìn ikú rẹ̀ ṣì kàmọ̀mọ̀.
  15. Kò ju ọmọ ogójì ọdún lọ tí ó fi jáde láyé.
  16. Inú ilé rẹ̀ tí ó kọ́ tí kò tíì gbé ni wọ́n sin òkú rẹ̀ sí.

Candidates who chose this question did not give detailed description of the character as regards the role he played in the text. This is due to lack of in-depth knowledge of the selected text.