Question 10
Nínú ewì “Obìnrin Ológo”, kí ni àwọn ohun tí Akéwì sọ pé kì í jẹ́ kí obìnrin di ológo?
Observation
Candidates were required to mention the various vices that could prevent a woman from becoming a glorious woman in “Obìnrin Ológo”.
Àwọn ohun tí akéwì sọ pé kì í jẹ́ kí obìnrin di ológo nínú ewì “Obìnrin Ológo” ni:
- Kí obìnrin máa sá fún ẹni tó lè ṣe é lóore.
- Ìwà àgbèrè.
- Kí obìnrin máa bú ènìyàn.
- Èpè ṣíṣẹ́.
- Òògùn ìkà ṣíṣe.
- Kí obìnrin máa lo orí ọkọ rẹ̀.
- Kí obìnrin má gbà fún Olúwa.
- Kí obìnrin má tọ́jú ọkọ àti ọmọ rẹ̀.
- Àìfi ìwà ọ̀yàyà bá ẹbí ọkọ lò.
- Àìkọbíara sí àdúrà gbígbà.
General guesses were made on various vices that can prevent a woman from being glorious but not as evident in the written poem.