Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2018

Question 12

    Ṣe àlàyé ṣókí-ṣókí lórí àwọn wọ̀nyí nínú àṣà ìgbéyàwó ìbílẹ̀: ìfojúsóde; ìtọrọ; ìwádìí; owó ìjọ́hẹn, aṣọ ìbálé.


Observation

Candidates were required to describe the above as steps in traditional Yorùbá marriage practices.
 

  1. Ìfojúsóde: ọ̀nà tí à ń gbà wá ìyàwó fún ọmọkùnrin tàbí ọkọ fún ọmọbìnrin tí ó ti bàlágà tó sì ti tójú bọ́. Ẹbi, ará, ọ̀rẹ́ tàbí ẹni tí ọ̀rọ̀ kàn lè fi ojú sóde.
  1. Ìtọrọ: Lílọ tí àwọn mọ̀lẹ́bí ọmọkùnrin máa lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí ọmọbìnrin láti fi ìfẹ́ wọn hàn pé àwọn fẹ́ fi ọmọbìnrin wọn ṣe aya.

 

  1. Ìwádìí: èyí ni ìwádìí tí àwọn òbí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin máa ń ṣe nípa mọ̀lẹ́bí ẹni tí ọmọ wọn fẹ́ fẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá ilé tó ṣeé yà sí ni ọmọ náà ti wá. A lè ṣe ìwádìí yìí lẹ́nu àwọn ará ìlú tàbí lẹ́nu Ifá. Bí àbájáde ìwádìí bá ṣe ẹnu ire, wọn yóò tẹ̀síwájú.
  1. Owó ìjọ́hẹn: èyí ni owó tí ọmọkùnrin gbọ́dọ̀ san lọ́gán tí ìyàwó àfẹ́sọ́nà rẹ̀ bá ti gbà tàbí ‘jọ́hẹn’ fún un láti fẹ́ ẹ.

 

  1. Aṣọ Ìbálé: ni aṣọ funfun tí ọkọ ìyàwó yóò fi nu ẹ̀jẹ̀ ìbálé ìyàwó rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá jọ ‘sùn’ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn. Aṣọ yìí ló máa ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé wọ́n bá ìyàwó ‘nílé’!

Most of the candidates who attempted this question reiterated modern practices instead of the traditional.