Question 13
Ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bí a ṣe ń lo ológò láti gba gbèsè láàrin àwọn Yorùbá ní ìgbà àtijọ́.
Observation
Candidates were required to explain ways of retrieving bad debts in traditional Yorùbá society.
Bí a ṣe ń lo Ológò/Adógò láti gba gbèsè láàrin àwọn Yorùbá ní ìgbà àtijọ́:
- Ológò/Adógo ni ẹni tí à ń lò láti gba gbèsè tí ẹni tí ó jẹ ni lówó kò bá fẹ́ẹ́ san owó náà.
- Olówó yóò rán ológò lọ sílé ajẹgbèsè láti lọ bá òun gba owó náà tipátipá.
- Àwọn tí a máa ń sáàbàá lò láti dógò ni àwọn alárùn bí ológòdò, adẹ́tẹ̀ àti eĺégbò ńlá.
- Ológò lè jẹ́ ẹlẹ́kẹ̀ẹ́ èébú tí ó lè bú ènìyàn dáradára, kí ó sì fi í ṣe ẹ̀sín/yẹ̀yẹ́.
- Bí ológò bá délé ajẹgbèsè, yóò dógò tì í títí tí yóò fi wá owó náà san.
- Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ológò lè gbà dààmú ajẹgbèsè títí tí yóò fi rí owó náà san.
- Ológò lè má jẹ́ kí ajẹgbèsè jẹun; o lè ṣe ọ̀bùn sínú ilé ajẹgbèsè; ó lè sún sórí ibùsùn kan náà pẹ̀lú ajẹgbèsè.
- Bí ológò ti ń fòòró ẹ̀mí ajẹgbèsè ni yóò máa fòòró ẹ̀mí àwọn ará ilé rẹ̀ pẹ̀lú.
- Nígbà tí wàhálà bá sú àwọn ará ilé ajẹgbèsè, wọ́n lè dá owó náà jọ láti san gbèsè náà.
- Lára owó tí ológò bá gbà fún olówó ni olówo yóò ti yọ owó ọ̀yà rẹ̀ fún un.
Most candidates mistook Òṣómàáló for Ológo/Adógo. Ológo is a hired debt collector while Òṣómàáló is an Ìjẹ̀ṣà creditor who forcefully retrieves debt.