Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 2ND), 2018

Question 11

    Ṣàlàyé ìtàkurọ̀sọ tí ó wáyé láàrin Ṣọlá àti Kúnbi lẹ́yìn ìgbéyàwó ṣọlá.


Observation

Candidates were expected to recall the dialogue between Ṣọlá and Kúnbi after the former’s wedding.
Ìtàkurọ̀sọ tí ó wáyé láàrin Ṣọlá àti Kúnbi lẹ́yìn ìgbéyàwó Ṣọlá:

  1. Kúnbi lọ kí Ṣọlá ní ilé lẹ́yìn ìgbéyàwó Ṣọlá.
  2. Ṣọlá sọ èròǹgbà lílọ sí ìlú Òyìnbó rẹ̀ fún Kúnbi.
  3. Ó ṣàlàyé bí ọkọ rẹ̀, Fẹ́mi, ṣe ń tọ́jú rẹ̀ tó.
  4. Ìlara kò jẹ́ kí inú Kúnbi dùn sí gbogbo ohun tí Ṣọlá ń sọ.
  5. Ṣọlá béèrè lọ́wọ́ Kúnbi nípa àwọn ọ̀rẹ́kùnrin tí ó ń kó kiri.
  6. Kúnbi ṣàlàyé fún Ṣọlá ìdí tí gbogbo wọn fi já òun jù sílẹ̀.
  7. Ṣọlá fi àìdunnú rẹ̀ hàn sí Kúnbi nípa bí ó ṣe bá ara rẹ̀ jẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn.
  8. Ó ní ọmọ onílé ọlọ́nà tó yẹ kí wọ́n máa jí tanná wò ni Kúnbi ṣùgbọ́n ó sọra rẹ̀ di ọmọ orí ìrìn.
  9. Ó ní ó burú jáì pé gbogbo àwọn tí ó yẹ kí Kúnbi fi ṣe ọkọ ni ó ti gbé ní àgbéjùsílẹ̀.
  10. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ṣọlá bá Kúnbi sọ wọ̀nyí bí i nínú púpọ̀.
  11. Ó ní ṣé nítorí pé Ṣọlá ti ní ọkọ ni ó ṣe ń sọ̀rọ̀ sí òun ṣákaṣàka báyẹn?
  12. Ṣọlá bẹ Kúnbi pé kí ó má bínú.
  13. Ó ní nítorí òun ti kà á kún ọmọ-ìyá òun ni òun ṣe bá a sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.
  14. Ó gbàdúrà pé Ọlọ́run á pèsè ọkọ tirẹ̀ fún un.

Recall of the dialogue was poorly handled by the candidates. Most candidates recalled faintly on how Kúnbi’s character usurped Ṣọlá’s position.