Question 6
Nínú ìtàn Ìjàpá àti Ẹyẹ Àdàbà, sàlàyé bí Ìjàpá ṣe fi ìlara pa ara rẹ̀.
Observation
Candidates were required to narrate how Ìjàpà one of the actors in the folktale killed himself as a result of envy.
Bí Ìjàpá ṣe fi ìlara pa ara rẹ̀:
(i) Ní ayé àtijọ́, Ìjàpá àti ẹyẹ Àdàbà jọ ń ṣe ọ̀rẹ́.
(ii) Alágàbàgebè, olè àti ọ̀kánjúà ni Ìjàpá.
(iii) Àdàbà ní ẹṣin kan tí ó máa ń gùn kiri tí Ìjàpá kò sì ní nǹkan kan.
(iv) Ìjàpá gbèrò bí yóò ṣe pa ẹṣin Àdàbà torí pé ó mú kí Àdàbà gbayì láàrín àwùjọ, èyí kò dùn mọ́ Ìjàpá nínú.
(v) Ní ọjọ́ kan, Ìjàpá fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí pa ẹṣin Àdàbà.
(vi) Àdàbà kò bínú sí kíkú tí ẹṣin rẹ̀ kú.
(vii) Dípò kí ó bínú, ó gé orí ẹṣin náà, ó bò ó mọ́lẹ̀.
(viii) Ó wá fi ojú ẹṣin náà sí ìta kí ènìyàn lè máa rí i dáadáa.
(ix) Bí Ìjàpá ti ń kọjá lọ ni o rí ojú tí ó yọ síta.
(x) Eléyìí yà á lẹ́nu, kíá ó gbéra, ó dilé ọba.
(xi) Nígbà tí ó dé ilé ọba, ó sọ fún ọba pé òun ti rí ibi tí ilẹ̀ gbé lójú.
(xii) Eléyìí ya ọba lẹ́nu, ó sì tún bi Ìjàpá bóyá ohun tí ó ń sọ dá a lójú.
(xiii) Ìjàpá fi dá ọba lójú pé òótọ́ ni àti pé kí ọba pa òun bí kò bá rí bẹ́ẹ̀.
(xiv) Nígbà yìí ni ọba pe gbogbo ìjòyè àti ẹmẹ̀wá rẹ̀ pé kí àwọn lọ wo ibi tí ilẹ̀ gbé lójú.
(xv) Ìjàpá ni ó ṣiwájú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọrin báyìí pé:
Lílé: Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Ègbè:Ilẹ̀
(xvi) Báyìí ni gbogbo wọn dà rẹirẹi lọ sí “ibi tí ilẹ̀ gbé lójú”.
(xvii) Bí Àdàbà ṣe gbọ́ ohun tí Ìjàpá ṣe yìí ni ó bá sáré lọ sí ibi tí ó bo orí ẹṣin rẹ̀ mọ́.
(xviii) Ó bá wú orí náà kúrò lọ sí ibòmíràn.
(xix) Ọba, ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ kò rí nǹkan kan nígbà tí wọ́n dé ibi tí Ìjàpà wí.
(xx) Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ síí túlẹ̀ kiri títí ṣùgbọ́n kò rí ojú kankan.
(xxi) Ọba bínú pé Ìjàpá pa irú irọ́ báyìí fún òun àti àwọn ị̀jòye òun.
(xxii) Kíá ni ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ó ti ojú Ìjàpá yọ idà kí wọ́n sì ti ẹ̀yin rẹ̀ kì í bọ àkọ̀ rẹ̀.
(xxiii) Báyìí ni Ìjàpá ṣe fi ìlara pa ara rẹ̀.
The folktale was not properly retold by most Candidates, revealing a lack of proper study of the text.