Question 7
Nínú oríkì Ìran Ológbì-ín, ṣàlàyé bí a ṣe mọ ẹni tí o ni eégún.
Observation
Candidates were required to narrate the tale of how the owner of the masquerade was identified in the lineage of Ológbì-ín.
Bí a ṣe mọ ẹni tó ni eégún nínú oríkì “Ìran Ológbìn-ín”:
- Àríyànjiyàn wáyé lórí ẹni tí ó ni eégún.
- Ọlọ́pọndà lóun ni òun ni eégún.
- Ẹ̀sà Ọ̀gbín lóun ni òun ni eégún.
- Ọlọ́jọwọ̀n náà lòun ni òun ni eègún.
- Aláràn-án náà ní òun lòun ni eégún.
- Èyí sì fa ìjà láàrin wọn.
- Wọ́n kó ara wọn lọ síwájú Aláàfin Ọ̀yọ́.
- Aláàfin Ọ̀yọ́ ní kí wọ́n ta kókó aṣọ.
- Kí wọ́n sì máa bọ̀ ní ààfin òun ní ọjọ́ keje.
- Gbogbo wọn ni wọ́n ta kókó aṣọ.
- Nígbà tó di ọjọ́ keje, wọ́n wá síwájú Abíọ́dún.
- Aláàfin ní kí gbogbo wọ́n jó, kí wọ́n ṣìju agọ̀ sílẹ̀.
- Bí Ọlọ́pọndà ṣe ṣíjú agọ̀ sílẹ̀, omi ni wọ́n bá nínú aṣọ.
- Wọ́n ni Ọlọ́pọ́ndà kọ́ ni ó ni eégún.
- Bí Aláràn-án ṣe ṣíjú agọ̀ sílẹ̀, igba abẹ́rẹ́ ni wọ́n bá létí aṣọ.
- Wọ́n ní Aláràn-án kọ́ ló ni eégún àti pé àrán ni ó lè rán.
- Bí Làgbàyí ọmọ ọ̀nà L’árè ṣe ṣíjú agọ̀ sílẹ̀, igi pẹlẹbẹ pẹlebẹ ni wọ́n bá létí aṣọ.
- Wọ́n ní igi lọmọ olórí ọlọ́nà ń gbẹ́.
- Bí Ẹ̀sà Ògbìn Ológbojò ṣe ṣị́jú agọ̀ sílẹ̀ gbugudu, igba eégún wẹẹrẹwẹ la bá nínú aṣọ.
- Wọ́n bá ni Ológbojò, òun gan-an lo ni eégún.
- Báyìí ni a ṣe mọ ẹni tí ó ni eégún.
Candidates’ performance was poor in this question. This suggests that candidates lack exposure to the selected text.