Question 10
Mẹ́nuba àwọn ọ̀nà tí pẹ̀gànpẹ̀gàn ń gbà pẹ̀gàn nínú ewì “Pẹ̀gànpẹ̀gàn”
Observation
Candidates were required to describe ways by which mockers make a mockery of people around them as evident in the poem “Pẹ̀gànpẹ̀gàn”.
Àwọn ọ̀nà tí pẹ̀gànpẹ̀gàn ń gbà pẹ̀gàn nínú ewì “Pẹ̀gànpẹ̀gàn”:
- Bí wọ́n bímọ ládùúgbò bí ó bá jẹ́ abo tí gbogbo ènìyàn ń dunnú, pẹ̀gànpẹ̀gàn á ní ṣèbí obìnrin atẹ̀yìntọ̀ lásánlàsàn ni ó bí.
- Bí wọ́n bá bímọ ọkùnrin tí wọ́n ń dunnú, pẹ̀gànpẹ̀gàn lè ní ṣé gómìnà ni wọ́n bí ni?
- Bí ènìyàn ṣe ìdánwò tí ó yege/rọ́wọ́ mú nílé-ẹ̀kọ́, pẹ̀gànpẹ̀gàn á ní ṣe ni ó gbéégún/jí ìwé wò.
- Bí ènìyàn kàwé tí ó níwèé-ẹ̀rí tó dáa lọ́wọ́, ẹlẹ́gàn á fi wé ẹni tí ó ṣe ayédèrú ìwé-ẹ̀rí.
- Bí oníṣòwò kan bá ń tajà ní ẹ̀dínwó tí oníbàárà rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀ dénú, pẹ̀gànpẹ̀gàn á ní irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti rí ayédèrú/ọjà rọ̀bìrọ̀bì/fàyàwọ́ rà ni.
- Ẹni tí ó bá jẹ́ obìnrin rere lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ, pẹ̀gànpẹ̀gàn á ní ó ti ya dìndìnrìn.
- Bí ènìyàn bá jẹ́ akínkanjú lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba, pẹ̀gànpẹ̀gàn á ní ẹrú ọ̀gá ni ẹni náà/olúwa rẹ̀.
- Bí ènìyàn bá lawọ́, pẹ̀gànpẹ̀gàn á ní ó fi ń gbéra ga ni.
- Bí ènìyàn sì jẹ́ aṣọ́wóná, pẹ̀gànpẹ̀gàn á ní ahun ni ẹni náà.
- ‘Apatọ́rọ́-da-náhín-sígbó’ lorúkọ àbísọ rẹ̀.
Candidates’ performance was poor, general guesses were made and not as evident in the text.