Question 8
Sọ ìtan àwọn ẹrú tí asùnrèmọ̀jé sọ pé bàbá wọn rà láti orí Adìẹ títí dé orí Táńdí
Observation
Candidates were required to narrate how the father of the chanter bought different slaves from “Adìẹ to Táńdí” as evident in the excerpt
Ìtàn àwọṅ ẹrú tí asùnrèmọ̀jé sọ pé bàbá wọ́n rà láti orí Adìẹ títí dé Táńdí:
- Adìẹ òkòkò ni ẹrú àkọ́rà babaa wọn.
- Ó yógún, ó pogún.
- Wọ́n ládìẹ ò pa ọmọ re.
- Wọ́n gbé adìẹ tà.
- Wọ́n fowó rawó.
- Awó yẹ́yin méjì, ó pà kan.
- Ó fẹ̀sín há párá, ó ń ṣẹlẹ́yà adìẹ.
- Wọ́n gbé awó tà.
- Wọ́n lọ rèé rajá, wọ́n sọ ọ́ ní Tańmẹ̀dá.
- Ajá bímọ mẹ́fà, ó kù kan.
- A gbájá tà.
- Wọ́n ra ọ̀bọ.
- Ọ̀bọ ò bímọ kọ̀ọ́ọ̀kan.
- Wọ́n gbé ọ̀bọ tà.
- Wọ́n ra Táńdí ṣùgbọ́n kò lè roko.
Only a few number of the candidates attempted this question. Their responses to this question portrayed failure to study the particular text.