Question 13
Sọ̀rọ̀ lórí eré òkòtó
Observation
Candidates were required to discuss “eré òkòtó”, one of the forms of moonlight games among the Yorubas..
Eré Òkòtó:
- Ó jẹ́ eré ìdárayá/ìdíje fún àwọn ọ̀dọ́.
- A lè ta á nínú ilé tàbí ní gban̄gba.
- Orí èrùpẹ̀ tàbí iyanrìn tí ó kúnná ni a ti ń ta á.
- Ìkarahun ìlákọ̀ṣẹ/ìgbín kékeré/páànù fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ni a fi ń ṣe òkòtó.
- Ènìyàn méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló máa ń ta òkòtó fún ìdíje.
- Tọkùnrin tobìnrin ló máa ń ta á.
- Òkòtó títa ní òfin tí ó dè é.
- Bí ológò ti ń fòòró ẹ̀mí ajẹgbèsè ni yóò máa fòòró ẹ̀mí àwọn ará ilé rẹ̀ pẹ̀lú.
- Oríṣi gígán méjì ló wà nínú òkòtó títa:(a) kon̄ko/ gbáro, (b) tùjẹ̀.
- Òkòtó títa lè dìjà.
- Ó máa ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ nípa mímọ ọwọ́ yíyí padà.
- Ó ń fún ọ̀dọ́/ọmọdé ní ẹ̀mí ìfaradà.
- Ó ń kọ́ wọn ní bí a ṣe ń ṣe àkíyèsí.
- Ó ń mú kí ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán wà láàrin àwọn ọmọdé.
- A máa ń fi òkòtó dárà.
Some of the candidates who attempted this question could not give the step by step procedure on how to play this moonlight game.