Question 12
Báwo ni àwọn Yorùbá ṣe ń pa eyín fi ṣe aájò ẹwà?
Observation
Candidates were required to describe how teeth filing is being done among the Yorubas as a means of beautification.
Eyín pípa gẹ́gẹ́ bí aájò ẹwà nílẹ̀ Yorùbá:
- Eyín pípa jẹ́ ọ̀nà kan láti fara wé àwọn tí ó pa èjí wá láti ọ̀run tí ẹwà wọn sì máa ń dá ènìyàn lọ́rùn.
- Àwọn ọ̀dọ́ tí ó gbáfẹ́ ni ó sábà máa ń pa eyín.
- Tọkùnrin tobìnrin ni ó máa ń kọ́ àṣà eyín pípa.
- Ìkọ tàbí ayùn kékeré ni àwọn Yorùbá fi ń pa eyín wọn.
- Bí a bá fẹ́ pa eyín fún ẹni kan, a ó dá a dùbúlẹ̀, yóò sì ṣí eyín rẹ̀ síta.
- Payínpayín náà yóò sì máa fi ìkọ/ayùn kékeré ọwọ́ rẹ̀ gbẹ́ àárín eyín méjì òkè títí tí yóò fi ní àlàfo díẹ̀ láàárín.
- Eyín pípa mú ìrora díẹ̀ dání.
- Ó lè fa ìpalára bá ẹsẹ̀ eyín; kòkòrò sì lè wọ̀ ọ́ kí ó wá di egbò.
- Bí ọ̀rọ̀ ilà kíkọ ni ó rí; bí ó bá jiná tán ni Yorùbá gbà pé ó máa ń bu ẹwà kún ara
.
Most candidates who attempted this question could not describe how teeth is being filed, this led to poor performance.