Question 6
Nínú ìtàn “Ìjàpá àti Bùjé”, ọ̀nà wo ni Ìjàpá gbà dójú ti Bùjé?
Observation
Candidates were required to explain how a character, Ìjàpá, disgraced another character, Bùjé, who was too pompous in the folktale “Ìjàpá àti Bùjé.
Ọ̀nà tí Ìjàpá gbà dójú ti Bùjé nínú ìtàn “Ìjàpá àti Bùjé”:
(i) Ọmọbìnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kerebùjé tí àgékúrú rẹ̀ ń jẹ́ Bùjé.
(ii) Ọmọbìnrin náà lẹ́wà púpọ̀.
(iii) Ọmọbìnrin náà ní ìgbéraga púpọ̀.
(iv) Ó ń fọ́ọnu kiri pé kò sí ọkùnrin kan ní ìlú àwọn tí ó lè rí ìhòhò òun.
(v) Ìjàpá gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Bùjé sọ, ó sì pinnu láti já ọ̀rọ̀ Bùjé.
(vi) Ìjàpá ṣọ́ Bùjé dáadáa, ó sì mọ ojú ọ̀nà tí ó máa ń gbà.
(vii) Ìjàpá lọọ dá oko kan sí ẹ̀gbẹ́ ojú ọnà náà.
(viii) Ní ọjọ́ kan, Ìjàpá gbé òkú ejò kan dábùú ọ̀nà tí Bùjé yóò gbà kọjá.
(ix) Bí Bùjé ṣe ń lọ ni ó rí ejò tí ó dábùú ọ̀nà.
(x) Ó rò pé ààyè ejò ni láìmọ̀ pé òkú ni.
(xi) Bí Bùjé ti dé ibi tí ejò wà, ẹ̀rù bà á.
(xii) Bùjé pe Ìjàpá kí ó wá ran òun lọ́wọ́ láti pa ejò náà.
(xiii) Ìjàpá gbọ́ igbe Bùjé, ó sáré wá sí ojú ọ̀nà.
(xiv) Ìjàpá ṣe bí ẹni tó fẹ́ẹ́ pa ejò.
(xv) Ìjàpá da ẹ̀jẹ̀ tí ó ti gbà pamọ́ sínú igbá kan sí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣe bí ẹni pé òun ti gé ara òun ládàá.
(xvi) Ìjàpá fi igbe ta, ó sì ń kọrin pé: kí Bùjé gbé òun pọ̀ṅ; gbogbo ènìyàn sì pé lé wọn lórí.
(xvii) Àánú Ìjàpá ṣe àwọn ènìyàn, wọ́n rọ Bùjé pé kí ó ṣe ohun tí Ìjàpá wí; Bùjé gbà, ó sì fi aṣọ bò ìjàpá mọ́ra.
(xviii) Bí wọ́n ti rìn díẹ̀, Ìjàpá ní kí Bùjé gbé òun kalẹ̀, nìtori pe oun ti ri ìhòòhò rẹ̀ ná.
Candidates who read the text gave detailed explanation of how the pompous character was disgraced in the folktale “Ìjàpá àti Bùjé”.