Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2021

Question 13

Ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bí a ṣe ń sìnkú ẹni tí ààrá sán pa


Observation

 Candidates were required to describe the funeral rites of a victim of thunder strike.

Àlàyé lórí bí a ṣe ń sìnkú ẹni tí ààrá sán pa:

  1.      Ṣàngó ló ni ààrá, òun ni ó sì lágbára láti sán ààrá pa ènìyàn
  2.      Ẹni tí Ṣàngó bá ń bínú sí ni ó máa ń sán ààrá pa

(iii)     Ṣàngó kì í déédé rán ààrá láti pa ènìyàn, ó ní láti jẹ́ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti ṣe nǹkan búburú kan tí kò sì jẹ́wọ́
(iv)     Àwọn mọ̀gbà àti adóṣù Ṣàngó nìkan ni o lè wọ ilé ẹni tí ààrá bá sán pa
(v)      Gbogbo àwọn olùgbé ilé náà kò gbọdọ̀ wọ ilé/ fọwọ́ kan òkú tí ààrá sán pa títí     tí wọn yóò fi ṣe gbogbo ètùtù tó yẹ.
(vi)     Àwọn adóṣù Ṣàngó yóò yọ ẹdun ààrá níbi tí ó wọlẹ̀ sí kí wọ́n tóó sin òkú náà
(vii)    Ọjọ́ méje gbáko ni àwọn adóṣù Ṣàngó yóò fi ṣe ètùtù
(viii)   Ọdọ̀ àwọn aládùúgbò tàbí àwọn ọ̀rẹ́ ni àwọn olùgbé ilé náà yóò fara pamọ́ sí títí tí ọjọ́ méje yóò fi kọjá
(ix)     Mọ̀lẹ́bí òkú ni yóò ra àwọn nǹkan ètùtù
(x)      Ọkà/àmàlà àti ọbẹ̀ gbẹ̀gìrì ni àwọn mọ̀lẹ́bí òkú yóò fi máa bọ́ àwọn oníṣàngó fún ọjọ́ méjèèje tí wọn yóò fi ṣe ètùtù
(xi)     Ìrọ̀lẹ́-ìrọ̀lẹ́ ni àwọn mọ̀lẹ́bí òkú yóò máa jó kiri àdúgbò títí tí ọjọ́ méjèèje yóò fi      kọjá
(xii)    Àwọn alágbẹ̀dẹ tí ó wà ládùúgbò ni àwọn ẹbí yóò bẹ̀ láti máa lu ọmọ-owú tẹ̀lé wọn
(xiii)   Odò tí ó bá sún mọ́ ilé náà ni wọ́n gbọ́dọ̀ parí ijó náà sí ní ọjọ́ keje
(xiv)   Wọn yóò ṣanpá ṣansẹ̀ wọn nínú odò náà láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Ṣàngó
(xv)    Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé bí wọn kò bá ṣe gbogbo ètùtù wọ̀nyí, ikú náà lè di àkúfà nítorí pé Ṣàngó kò níí yéé jà nínú ìdílé náà.

         Some of the candidates who attempted this question performed poorly.