Yoruba Paper 2, Private Candidates 2019

Question 6

 

Nínú ìtàn “Ẹyẹ Àgbìgbò àti Obìnrin Méjì”, sọ ohun tí ó ṣokùnfà ikú ọmọ ìyáálé.
Candidates were required to explain what caused the death of the eldest wife’s child in the folktale “Ẹyẹ Àgbìgbò àti Obìnrin Méjì”.

Ohun tí ó ṣokùnfà ikú ọmọ ìyáálé nínú ìtàn “Ẹyẹ Àgbìgbò àti Obìnrin Méjì”:
(i) Ọkùnrin kan ní ìyàwó méjì.

(ii) Ìyáálé lówó, ìyàwó sì jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́.

(iii) Ewé ni akúṣẹ̀ẹ́ yìí máa ń ṣà kiri inú igbó.

(iv) Lọ́jọ́ kan, ó lọ ṣà ewé nínú igbó, ẹyẹ Àgbìgbò bá fò wá gbé ọmọ obìnrin yìí tó tẹ́ sí abẹ́ igi.

(v) Àgbìgbò gbé ọmọ yìí lọ sórí igi.

(vi) Nígbà tí ó ṣe tán, kò rí ọmọ rẹ̀ níbi tí ó tẹ́ ẹ sí mọ́.

(vii) Níbi tí ó ti ń wá ọmọ rẹ̀ ló rí i lórí igi tí ẹyẹ Àgbìgbò gbé e lọ.

(viii) Obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ síí sunkún, ó sì ń bẹ ẹyẹ Àgbìgbò.

(ix) Obìnrin náà ń kọrin bẹ ẹyẹ Àgbìgbò báyìí pé:
Lílé: Àgbìgbò gbọ́mọ̀ mi kòmí ìgbò
Ègbè: Ẹẹyẹ ìgbò...

(x) Nígbà tí ó pẹ́, ẹyẹ Àgbìgbò bi obìnrin náà pé ṣé yóò gba owó dípò ọmọ rẹ̀.

(xi) Obìnrin yìí kọ̀ ó ní ọmọ òun nìkan ló lè tẹ́ òun lọ́rùn.

(xii) Ẹyẹ Àgbìgbò fún obìnrin yìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó àti ẹrù, ó sì tún gbé ọmọ rẹ̀ fún un.

(xiii) Obìnrin yìí dá gbogbo ohun tí ẹyẹ Àgbìgbò fún un sí méjì, ó kó apá kan fún ìyáálé rẹ̀.

(xiv) Èyí kò dùn mọ́ ìyáálé yìí nínú nítorí ìwà ọ̀kánjúà rẹ̀.

(xv) Ó ní òun náà yóò lọ gba tòun l’ọ́dọ̀ ẹyẹ Ìgbò.

(xvi) Ó gbé ọmọ rẹ̀ ó di inú igbó.

(xvii) Bó ṣe dé inú igbó, ó ń ṣa ewé kiri bí i ti èkejì rẹ̀, ó sì tẹ́ ọmọ rẹ̀ sábẹ́ igi.

(xviii) Ẹyẹ Àgbìgbò kò gbé ọmọ rẹ̀.

(xix) Obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ síí bẹ ẹyẹ náà láti wáá gbé ọmọ òun kóun náà lè di ọlọ́lá bíi ìyàwó òun.

(xx) Ẹyẹ yìí mọ pé òjòwú ni obìnrin náà.

(xxi) Ẹyẹ yìí pinnu láti kọ́ ọ lọ́gbọ́n.

(xxii) Ó bá lọ gbé ọmọ rẹ̀.

(xxiii) Ẹyẹ yìí béèrè ohun tó fẹ́.

(xxiv) Ó ní òun fẹ́ kí ó sọ òun di ọlọ́rọ̀ bí ti ìyàwó òun.

(xxv) Ẹyẹ yìí fa itan ọmọ rẹ̀ kan ya, ó sọ ọ́ sí i.

(xxvi) Obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ síí bẹ ẹyẹ yìí pé owó ni òun fẹ́.

(xxvii) Ẹyẹ Àgbìgbò tún fa itan ọmọ rẹ̀ kejì ya, ó tún sọ ọ́ sí i.

(xxviii) Obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí sun ẹkún, ó ń gbé ara yílẹ̀.

(xxix) Ẹyẹ yìí sọ ìyókù ọmọ rẹ̀ sí i, ó sì fò lọ!

(xxx) Báyìí ni òjòwúbìnrin yìí ṣe pàdánù ọmọ rẹ̀ nítorí owú jíjẹ.

Observation

 

Candidates who read the text gave detailed explanations.