Yoruba Paper 2, Private Candidates 2019

Question 9

 

Ṣe àlàyé ìbáṣepọ̀ tí ó wà láààrín Òbí àti Mopélọ́lá.
Candidates were expected to describe the relationship between the two characters as seen in the novel.

Ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín Òbí àti Mopélọ́lá:
(i) Mopélọ́lá ni olólùfẹ́ Òbí àkọ́kọ́.

(ii) Òbí ṣe alábàápàdé Mopélọ́lá nígbà àkọ́kọ́ ní abà tí Òbí ti lọ ṣe àgbàro.

(iii) Ní àsìkò yìí, Òbí ṣe ìwádìí nípa Mopélọ́lá ní abà.

(iv) Òbí wá ọ̀nà láti bá Mopélọ́la sọ̀rọ̀.

(v) Òbí bá Mopélọ́lá sọ̀rọ̀, ó sì mọ̀ pé ilé-ẹ̀kọ́ Mọdá ló wà.

(vi) Òbí wá Mopélọ́lá lọ sí ilé.

(vii) Mopélọ́lá ṣe Òbí lálejò.

(viii) Òbí dẹnu ìfẹ́ kọ Mopélọ́lá.

(ix) Mopélọ́lá kọ́kọ́ sọ pé òun ti ní ẹnìkan.

(x) Mopélọ́lá tún padà sọ pé òun kéré.

(xi) Mopélọ́lá sọ fún Òbí pé òun náà ní ìfẹ́ rẹ̀.

(xii) Àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́ ìmùlẹ̀.

(xiii) Àwọn òbí Mopélọ́lá fẹ́ràn Òbí.

(xiv) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Mopélọ́lá àti Òbí máa ń ṣeré jáde.

(xv) Rírò ni tènìyàn, Mopélọ́lá kò padà fẹ́ Òbí.

(xvi) Ẹ̀gbọ́n Òbí kan ni Mopélọ́lá fẹ́, ọmo Ìjọ wọn ni òun í ṣe.

(xvii) Èyí ni ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín Òbí àti Mopélọ́lá.

Observation

 

Candidates’ performance in this question was commended by the chief examiner.