Yoruba Paper 2, Private Candidates 2019

Question 8

 

“Ìrèmọ̀jé kì í ṣorin ìgbàkúùgbà”, ṣàláyé ìsọ yìí.
Candidates were required to explain the excerpts from the text: “Ìrèmọ̀jé kì í ṣorin ìgbàkúùgbà”.

Àlàyé “Ìrèmọ̀jé kì í ṣorin ìgbàkúùgbà”
(i) Ìrèmọ̀jé ni ó wà fún orò ìṣípà ọdẹ tí ó bá kú.

(ii) Ìrèmọ̀jé kì í ṣe orin ọdẹ lásán irú èyí tí a lè kọ nígbàkúùgbà tí orin bá wu nií kọ bí a ti ṣe lè sun ìjálá.

(iii) Ìrèmọ̀jé jẹ́ orin arò àti orin àkanlẹ̀kọ ní àkókò àjálù fún ọdẹ.

(iv) Orin tí a kì í kọ lọ́sàn-án àfi lóru ni.

(v) Àwọn ẹgbẹ́ ọdẹ níláti fi Ìrèmọ̀jé pe àwọn òkú ọ̀run láti wá bá wọn lọ́wọ́ nínú orò ìṣípà.

(vi) Ìgbàgbọ́ wọn ni pé lóru ni àwọn òkú lè jí dìde láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú aráyé.

(vii) Èèwọ̀ ni kí ènìyàn rìn pàdé ìpà ọdẹ.

(viii) Nítorí kí ènìyàn má lè rìn pàdé àgbákò yìí ni àwọn ọdẹ ṣe ń kó ìpà lóru.

(ix) Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé orin Ìrèmọ̀jé ni agbátẹrù orò ìṣípà, dandan ni àkókò tí à ń ṣípà ni orin Ìrèmọ̀jé ní láti wáyé.

(x) Àwọn onírèmọ̀jé á máa kọrin báyìí pé:
Ìrèmọ̀jé kì í ṣ’orin ìgbàkúùgbà,
Orin tá ì í kọ lọ́sàn-án àfi lóru ni.

(xi) Ìdí nìyí tó fi jẹ́ pé òru ni à ń kọ orin ìrèmọ̀jé.

Observation

 

Only a few number of the candidates attempted this question. Their responses to this question portrayed failure to study the particular text.