Question 12
Ṣàlàyé ìwúlò èsúsú gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìranra-ẹni-lọ́wọ́ nínú àṣà ìbílẹ̀ Yorùbá
Observation
Candidates were required to explain the importance of contributory scheme in the Yoruba traditional custom.
Ìwúlò Èsúsú gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà Ìranraẹni-lọ́wọ́:
- Èsúsú jẹ́ ọ̀nà kan tí à ń gbà fi owó pamọ́ fún níná lọ́jọ́ iwájú/ọ̀nà kan láti pọn omi sílẹ̀ de òǹgbẹ
- Ìbẹ̀rẹ̀ èésú dídá ni wọn yóò ti ṣe ìpinnu lórí iye ti ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa dá àti ọjọ́ tí wọn yóò máa kó èésú.
- Iye tí gbogbo ìjókòó bá fẹnu kò sí ni ẹnikọ̀ọ̀kan yóò máa kó
- Kò sí ẹni tí í kó èésú tán kí ó má dá èésú mọ́
- Olórí èésú ni alága èésú
- Ó máa ń fa ìrẹ́pọ̀ láàrin àwọn ènìyàn tó ń kópa nínú rẹ̀
- Ó máa ń jẹ́ kí ènìyàn múra sí iṣẹ́
- Ó máa ń jẹ́ kí akópa ṣeé fi ọkàn tán
- Ó máa ń bo àṣírí/ran àwọn akópa lọ́wọ́
- Ó máa ń jẹ́ kí ènìyàn kó ara rẹ̀ ní ìjánu/ ṣọ́ owó ná
- Ó máa ń tú àṣírí ẹni tí kò ṣeé bá dòwò pọ̀
- Ó fi ìran Yorùbá hàn gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ẹ̀dá tí ó ní àròjinlẹ̀/tí ó mọ̀ nípa pàtàkì ìfọwọ́wẹwọ́
- Ó máa ń ran akópa lọ́wọ́ láti gbé nǹkan rere ṣe lásìkò
- Kì í jẹ́ kí ìnáwó kankan bá wọn ní òjijì/ẹ̀jafùú
- Ó máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn akópa balẹ̀
Candidates who attempted this question performed fairly well.