Question 5
(a) Tọ́ka sí àpólà àpọ́nlé tí ó wà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan gbólóhùn wọ̀nyí:
(i) Màá ra aṣọ náà ní ìrọ̀lẹ́ ọ̀la.
(ii) Wọ́n gbà wá sí ilé wọn.
(iii) Ìyá ń gbàárù nítorí ọmọ.
(iv) Mo jẹ iyán gbígbóná ní ibi ayẹyẹ náà.
(v) Ọmọ náà dúdú bíi kóró iṣin.
(vi) Bádé jáde lọ ní òjijì.
(b) Irú àpólà àpọ́nlé ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́?
Observation
Candidates were required to identify adverbial phrasesin the sentences in (a)
and state the type of each of the adverbialphrases identified in (b).
Àpólà àpọ́nlé àti irúfẹ́ àpólà àpọ́nlé tí ó jẹ́ nínú gbólóhùn
S/N |
Àpólà àpọ́nlé inú gbólóhùn |
Irúfẹ́ àpólà àpọ́nlé tí ó jẹ́ |
i. |
ní ìrọ̀lẹ́ ọ̀la |
alásìkò |
ii. |
sí ilé wọn |
Oníbi |
iii. |
nítorí ọmọ |
onídìí/elérèdìí/onídìí abájọ |
iv. |
ní ibi ayẹyẹ náà |
Oníbi |
v. |
bí i kóró iṣin |
aláfiwé/aṣàfiwé |
vi. |
ní òjijì |
Oníbá |
Only a few of the candidates who tackled this question were able to state the types of verb phrases identified in (a).