Question 3
Ṣe àlàyé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ibi ìṣẹnupè wọ̀nyí kí o sì fi àpẹẹrẹ ìró méjì méjì tí a fi wọ́n gbé jáde gbe àlàyé rẹ lẹ́sẹ̀
(a) Àfèjìètèpè
(b) Àfèrìgìpè
(d) Àfàfàsépè
(e) Àfàjàfèrìgìpè
(ẹ) Àfàfàséfètèpè
Observation
Candidates were required to explain place of articulation and give two examples of sounds articulated in each place of articulation.
Àlàyé lórí ibi-ìṣẹ́nupè àti àpẹẹrẹ ìró tí a fi wọ́n gbé jáde
(a) Àfèjìètèpè:ni kọ́ńsónáǹtì tí a máa ń fi ètè méjéèjì pè (ètè òkè àti ètè ìsàlẹ̀). Àpẹẹrẹ, [b], [m] b, m.
(b) Àfèrìgìpè: ni ìró tí a máa ń fi ìgórí-ahọ́n/ iwájú-ahọ́n àti èrìgì pè. Àpẹẹrẹ, [t], [d], [s], [n], [ſ], [l], t, d, s, n, r, l.
(d) Àfàfàsépè: ni ìró tí a máa ń fi àfàsé àti ẹ́yín-ahọ́n pè. Àpẹẹrẹ, [k], [g], k, g.
(e) Àfàjàfèrìgìpè: ni ìró tí a máa ń fi apá ẹ̀yìn èrìgì àti apá iwájú àjà-ẹnu pẹ̀lú iwájú-ahọ́n pè. Àpẹẹrẹ [ʃ], [ɉ], ṣ, j.
(ẹ) Àfàfàséfètèpè: ni ìró tí a máa ń fi àfàsé àti ètè méjèèjì pẹ̀lú ẹ̀yìn ahọ́n pè. Àpẹẹrẹ, [kp], [gb], [w], p, gb, w.
Candidates who attempted this question tackled it wellin explaining the places of articulation and giving examples of sounds articulated at each place of articulation.