Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2021

Question 6

    Nínú ìtàn “Ìjàpá àti Alákàn”, báwo ni Alákàn ṣe gbẹ̀san ikú àwọn ọmọ rẹ̀ lára Ìjàpá?


Observation

Candidates were required to narrate the story of  how Alákàn, a character, in the folktale avenged the death of his children on Ìjàpá, their killer, in the folktale “Ìjàpá àti Alákàn.

Bí Alákàn ṣe gbẹ̀san ikú àwọn ọmọ rẹ̀ lára Ìjàpá:
(i)      Ní ìgbà kan rí Ìjàpá ń bá Alákàn ṣọ̀rẹ́
(ii)      Pẹjapẹja ni Alákàn ṣùgbọ́n àgbẹ̀ ni Ìjàpá
(iii)     Etí omi ni Alákàn ń gbé ṣùgbọ́n omi jìnnà sí ilé Ìjàpá. Nítorí náà Alákàn ni ó máa ń fún Ìjàpá lómi mu
(iv)     Alákàn bí ọmọ méje ṣùgbọ́n Ìjàpá kò bí
(v)      Èyí ń bí Ìjàpá nínú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí níí jowú ọ̀rẹ́ rẹ̀
(vi)     Ìjàpá pinnu làti pa àwọn ọmọ Alákàn méjèèje
(vii)    Ìyàn mú ní ìlú wọn débi pé Alákàn ni ó ń fún Ìjàpá ní omi; Ìjàpá náà sì ń fún Alákàn ní iṣu
(viii)   Ìjàpá ní/sọ pé kí Alákàn rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀lé òun láti gba iṣu
(ix)     Àbíkẹ́yìn Alákàn ni ó rán tẹ̀lé Ìjàpá láìmọ̀ pé Ìjàpá ti pinnu láti máa pa àwọn ọmọ òun jẹ
(x)      Ìjàpá ki ọmọ Alákàn tí ó rán tẹ̀lé e mọ́lẹ̀, ó sì pa á
(xi)     Alákàn kò rí ọmọ tí ó kọ́kọ́ rán níṣẹ́ kí ó dé, ó tún rán òmíràn títí dé orí àkọ́bí rẹ̀
(xii)    Báyìí ni ó ṣe bẹ̀rẹ̀ síí rán àwọn tí ó kù lọ́kọ̀ọ̀kan títí tí ó fi dé orí àkọ́bí rẹ̀
(xiii)   Gbogbo wọn pátá ni Ìjàpá pa jẹ
(xiv)   Alákàn wá sí ọ̀dọ̀ Ìjàpá láti béèrè àwọn ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n Ìjàpá sọ pé òun kò rí wọn
(xv)    Alákàn ṣèèṣì rí igbá ẹ̀yìn ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀yìnkùlé Ìjàpá ṣùgbọ́n kò sọ nǹkan kan
(xvi)   Alákàn pinnu láti gbẹ̀san lára Ìjàpá
(xvii)  Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Alákàn sọ fún Ìjàpá pé kí ó na orí rẹ̀ sínú ilé òun dáradára láti gba omi
(xviii)  Bí Ìjàpá ṣe na orí sínú ìhò, Alákàn fi amúga rẹ̀ gé e lórí sọnù
(xix)   Báyìí ni Alákàn ṣe gba ẹ̀san ikú àwọn ọmọ rẹ̀ lára Ìjàpá

Candidates who read the text gave detailed accounts of how Alákàn avenged the death of his children.