Question 8
Kí ni ó fàá tí Orò fi máa ń jáde ní òru nìkan?
Candidates were required to explain the reason why Oró goes out only at night.
Observation
Ìdí tí Orò fi máa ń jáde ní òru nìkan:
(i) Òrìṣà ni Egúngún àti Orò jẹ́ nígbà ìwáṣẹ̀
(ii) Ìbejì ni Egúngún àti Orò
(iii) Ọkùnrin ni àwọn méjèèjì
(iv) Orò lẹ̀gbọ́n, Egúngún làbúrò
(v) Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni àwọn méjèèjì ń ṣe
(vi) Ìyàwó wọn ni ó sì ń ta irè oko wọn lọ́dọọdún
(vii) Ìyàwó Egúngún ń fi owó díẹ̀díẹ̀ pamọ́, ó sì ń raṣọfún ọkọ rẹ̀
(viii) Onínà-án-kúnà-án obìnrin ni ìyàwó Orò, tìfun-lọ̀ràn ni, kì í rí owó fi pamọ́
(ix) Ìyàwó Orò kì í raṣọ fún ọkọ rẹ̀
(x) Ní ọjọ́ kan, Egúngún àti Orò fẹ́ẹ́ lọ sí òde
(xi) Egúngún kó sínú aṣọ tí ó jíire ṣùgbọ́n Orò kò rí aṣọ gidi kan wọ̀
(xii) Èyí mú kí Orò rí àṣìṣe aya rẹ̀
(xiii) Orò mú àtòrì rọ̀jọ̀rọ̀jọ̀, ó kó o bo ìyàwó rẹ̀
(xiv) Ìyàwó Orò sá, ó korí bọ igbó
(xv) Orò lé e kò bá a nítorí pé ìhòhò ni Orò wà
(xvi) Láti ìgbà náà ni Orò ti ń pe Ìyàwó yìí kágbó tí ó sì máa ń sọ pé ‘Bun-un-bun-un-bun-un’
(xvii) Egúngún a máa jáde láàárọ̀, lọ́sàn-án tàbí lálẹ́ nítorí pé aṣọ tí ó jíire ni ó máa ń wọ̀ sọ́rùn.
(xviii) Òru nìkan ni Orò fi ń rìn jáde nítorí ipò oníhòòhò tí ó máa ń wà
(xix) Ìdí nìyí tí Orò fi máa ń jáde ní òru nìkan.
Only a few candidates attempted this question. Their responses to this question portrayed failure to study the text.