Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2021

Question 7

Rọ́ ìtàn bí ọmọ Olókùn-Ẹṣin ṣe wáá rí iṣin rẹ̀ tà ní ọjà nínú oríkì “Ìran Ọmọ Olókùn-Ẹṣin.

Observation

Candidates were required to narrate how ọmọ Olókùn-Ẹṣin got to sell his wares as described in the poem of this lineage.
Bí ọmọ Olókùn-Ẹṣin e wáá rí iṣin rẹ̀ tà lọ́jà

  1. Ọmọ Olókùn-Ẹṣin kò mọ̀ pé àkúnlẹ̀ká ni wọ́n ń pe iṣin lóde Ìṣin
  2. Ó dúró dúró, ọwọ́ rẹ̀ kò tó iṣin
  3. Ó bẹ̀rẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ kò tó iṣin
  4. Àfi ìgbà tí ó dúbùú yẹ̀kẹ́ ni iṣin gbogbo bá kún inú igbá titi
  5. Iṣin inú igbá yìí ni ó gbé lọ sí ọjà láti tà
  6. Ó gbé iṣin dọ́jà, iṣin ò tà
  7. Ó wá sunkún padà sílé
  8. Lójú òde ni ó ti pàdé bàbá arúgbó kan
  9. Bàbá yìí làgbà tí ó ń bẹ lọ́jà Ṣẹ̀kẹ̀
  10. Kẹ̀kẹ́ òwú ni ó ńgbé lọ sọ́jà bílẹ̀ bá ti mọ́
  11. Bójúmọ́ bá ti mọ́, igba igba ni ó ń ran tirẹ̀
  12. Bàbá arúgbó yìí làgbà tí ó n kọ́ni lọ́ràn bí ìwere ẹni
  13. Òun ló wádìí bí Olókùn-Ẹṣin ṣe ń polówó iṣin lóde Ìṣin
  14. Olókùn-Ẹṣin dáhùn, ó ní, òun ń polówó pé”Ẹ bá mi ra iṣin o! ẹ bá mi ra iṣin o!”
  15. Bàbá arúgbó yìí ní kí Olókùn-Ẹṣin tètè gbé iṣin náà padà sí ọjà
  16. Ó ní bí ó bá padà dé ọjà kí ó máa polówó pé “Ẹ bá mí ra àkúnlẹ̀ká o!”
  17. Bí Olókùn-Ẹṣin ti ń polówó àkúnlẹ̀ká ni wọ́n ń sáré bá a ra iṣin.
  18. Báyìí ni Olókùn-Ẹsin ṣe wárí iṣin rẹ̀ tà lọ́jà