Question 4
(a) Dárúkọ ìsọ̀rí-ọ̀rọ̀ tàbí ìsọ̀rí gírámà tí a fàlà sí nídìí nínú gbólóhùn wọ̀nyí:
(i) ọmọ náà sùn fọnfọn.
(ii) Olú àti Òjó lọ sí ọjà.
(iii) Ó dára láti máa ṣe rere.
(iv) Ẹ fun ún ní naira méjì.
(v) Ṣe bàbá máa wọ aṣọ tuntun?
(b) Lo ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀rọ̀ ìsàlẹ̀ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àbọ̀ nínú gbólóhùn
(i) agbára
(ii) ìlera
(iii) àdúrà
(iv) ọgbọ́n
(v) àánú
Observation
Candidates were required to identify the classes of words or grammatical categories in (a) and to use each of the words in (b) as objects in illustrative sentences.
(a)
Ọ̀rọ̀ tí a fàlà sí nídìí |
Ìsọ̀rí ọ̀rọ̀/ ìsọ̀rí gírámà tí ó wà |
náà |
ẹ̀yán/ẹ̀yán atọ́ka aṣàfihàn |
fọnfọn |
ọ̀rọ̀-àpọ́nlé |
àti |
ọ̀rọ̀-asopọ̀ |
sí |
ọ̀rọ̀-atọ́kùn |
dára |
ọ̀rọ̀-ìṣe |
rere |
ọ̀rọ̀-orúkọ |
un |
ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ |
méjì |
ẹ̀yán aṣòǹkà/ọ̀rọ̀-orúkọ |
ṣé |
atọ́ka/wúnrẹ̀n ìbéèrè/atọ́nà gbólóhùn/ẹ̀pọ́n gbólóhùn |
tuntun |
ọ̀rọ̀ àpèjúwe/ẹ̀yán aṣàpèjúwe |
Many of the candidates who attempted this question performed fairly well.