Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2021

Question 9

Báwo ni Mosún olóòórùn ṣe di ẹni ẹ̀kọ̀ tí ayé ń sá fún láwùjọ?


Observation

Candidates were required to narrate how Mosun becameostracized due to her body odour.

Bí Mosún olóòórùn ṣe di ẹni ẹ̀kọ̀ tí ayé ń sá fún láwùjọ:

  1. Ọ̀kan lára àwọn Olóyè Ilẹ̀-Ifẹ̀tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún Àrólé ni bàbá Mosún yá èèbù iṣu bíi igba lọ́wọ́ rẹ̀
  2. Bàbá Mosún ṣèlérí fún Olóyè yìí pé òun yóò pa èèbù mìíràn fún un padà bí òun bá ti kórè iṣu òun ní àmọ́dún
  3. Ìrọ́dún ọ̀hún ni òjò ò tètè rọ̀ tí iṣu sì jọ́bà lébè
  4. Èyí mú kí bàbá Mosún má lè pa èèbù fún olóyè padà
  5. Olóyè bẹ̀rẹ̀ sí níí yọ bàbá Mosún lẹ́nu pé kí ó bá òun wá èèbù iṣu òun
  6. Fìtìnátì bàbá Olóyè yìí pọ̀ débi pé bàbá Mosún fi Mosún, ọmọ rẹ̀, ṣọfà fún un
  7. Bàbá Mosún ṣèlérí pé òun yóò wá gba ọmọ òun padà bí òun bá ti rí èèbù tó tó èyí tí òun gbà lọ́wọ́ Olóyè
  8. Pọn-nabọn ìyà ni bàbá olóyè yìí fi ń jẹ Mosún lásìkò tí ó ń ṣọfà lọ́dọ̀ rẹ̀
  9. Oúnje ẹ̀ẹ̀kan péré ni ó máa ń fún Mosún lóòjọ́, ọ̀sán nìkan sì ni
  10. Mosùn ni yóò mọ bí yóò ti jẹ oúnjẹ ti àárọ̀ àti ti alẹ́ fúnra rẹ̀
  11. Òru ọjọ́ kan ni bàbá Olóyè yìí yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ bá Mosún níbi tí ó sùn sí, ó sì bá a lájọṣepọ̀ tipátipá
  12. Lẹ́yìn èyí ni bàbá Olóyè kìlọ̀ fún Mosún pé kò gbọdọ̀ sọ àṣírí náà fún ẹnikẹ́ni àti pé ọjọ́ tí ó bá sọ ọ́ jáde ni yóò gba ọjọ́ ikú rẹ̀
  13. Láti ìgbà yìí ni bàbá Olóyè ti ń bá Mosún lájọṣepọ̀ lóòrèkóòrè
  14. Kò lọ́rún, kò lóṣù, Mosún fẹ́ra kù, ó sì fi tó bàbá Olóyè létí
  15. Bàbá Olóyè torí èyí lé Mosún jáde kúrò ní ilé rẹ̀
  16. Bàbá Mosún kò lè sa ipá kan lórí ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé Olóyè lágbára, ó sì lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ àti pé ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni ó jẹ́ fún Àrólé.
  17. Bàbá Mosún fi ọ̀rọ̀ mọ Olọ́run, ó sì ń kó ìtọ́jú Mosún bájú bámú títí di àkókò ìbímọ rẹ̀.
  18. Àwọn agbẹ̀bí sọ fún bàbá Mosún pé ọmọ rẹ̀ kò níí lè dá ọmọ náà bí fúnra rẹ̀ nítorí pé abẹ́ rẹ̀ fún, nítorí ọjọ́ orí rẹ̀ tí ó kéré àfi tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ abẹ fún un.
  19. Àsìkò ìbímọ yìí ni ìjàǹbá ṣe Mosún lójú ara tí kò le pa ìtọ̀ mọ́ra mọ́ tí ó sì ń ní ìsun ẹ̀jẹ̀ aláwọ̀ọ́ọ̀dá.
  20. Inú wàhálà àsáká yìí ni bàbá Mosún ti rí ikú rẹ̀ he; ṣe ni ó gbẹ̀mí ara rẹ̀.
  21. Láti ìgbà yìí ni Mosún ti di ẹlẹ́gbin, tí ó di olóòórùn tí ayé ń sá fún.

 

Candidates’ performance in this question was poor, it showed that Candidates had shallow knowledge of the set text.