Yoruba Paper 2 WASSCE (PC 1ST), 2021

Question 2

Kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní kíkún:
(a)      (i)      Òòṣà
          (ii)      Ọ̀ọ́kán
          (iii)     Èébú
          (iv)     Gbẹ́dó
          (v)      Etíkun
(b)     Ṣàlàyé ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí a lò láti ṣẹ̀dá àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí ó wà ní (a).


Observation

Candidates were required to write the base forms of the derived words in (a) and explain the phonological processes involved in deriving the words in (b).

 

Kíkọ ọ̀rọ̀ ní kíkún àti ṣíṣe àlàyé lórí àwọn ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí a lò láti ṣẹ̀dá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn

                   

S/N

Ọ̀rọ̀

(a)

(b)

 

Ìkọníkíkún

Ìgbésẹ̀ fonọ́lọ́jì tí a fi ṣẹ̀dá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn

i

òòṣà

òrìṣà

A pa ìró ‘r’ jẹ nínú òrìṣà, = òìṣà, a sọ ‘i’ di ‘ò’ nípasẹ̀ àrànmọ́= òòṣà

ii

ọ̀ọ́kán

ọ̀kánkán

A pa ìró ‘k’ àkọ́kọ́ jẹ láti ara ‘ọ̀kánkán’= ọ̀ánkán, a sọ ‘án’ dí ‘ọ́’ nípasẹ̀ àrànmọ́=ọ̀ọ́kán

iii

Èébú

Èbíbú

A pa ìró ‘b’ àkọ́kọ́ jẹ nínú èbíbú =èíbú, a sọ ‘í’ di ‘é’ nípasẹ̀ àrànmọ́ =èébú

iv

gbẹ́dó

gbẹ́ odó

A pa ìró ‘o’tí ó bẹ̀rẹ̀“odó” jẹ, ó wá di “gbẹ́ ‘dó”; ìsúnkì sọ ọ́ di gbẹ́dó

v

Etíkun

etí òkun

A pa ìró ‘ò’ tí ó bẹ̀rẹ̀ òkun jẹ́, ìsúnkì wá sọ “etí ‘kun” di etíkun.

Ìlù, ìlu, ijó, ìgbì, ike, irin, ìṣẹ́, iṣẹ́, ìrù, ibi, ìbí, ibí, ibo, ìbò, iṣu, iyọ̀, iwin, iyán

 

Many of the candidates who attempted this question performed averagely well as they could write out the basic words and explain the phonological processes involved in the derivation of the given words.