Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2022

Question 10

Àwọn ìmọ̀ràn wo ni Akéwì gbà wá lórí àwọn àkàndá nínú ewi “Àkàndá Fakọyọ”?

 

Observation

Candidates were required to mention various advices of the poet to the society on how to cater for the needs of the physically challenged in our society.

Àwọn ìmọ̀ràn tí akéwì gbà wá lórí àwọn Àkàndá ẹ̀dá:

  1. Kí á má fi ojú ẹ̀gàn wo àwọn àkàndá mọ́
  2. Kí á mọ̀ pé iṣẹ́ àrà ọwọ́ Olódùmarè ni wọ́n
  3. Kí á mọ̀ pé iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ni àwọn àkàndá wà fún
  4. Kí á mọ̀ pé àwọn àkàndá kan wà tí ìyá wọn kò bí wọn bẹ́ẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ pé kádàrá tí wọn kò lọ́nà ni ó sọ wọn di àkàndá
  5. Kí abarapá má ṣe fi àkàndá ṣẹ̀fẹ̀; kí a má fi àkàndá ṣe yẹ̀yẹ́ mọ́ nítorí pé a kò mọ ìpín tí àwa gan-an yàn
  6. Kí á mọ̀ pé kí ènìyàn jẹ́ àkàndá kò ní kí ó má dènìyàn pàtàkì láyé
  7. Gbogbo ẹni tí ó bá bí àkàndá kí ó má ṣe bò wọ́n mọ́lé
  8. Kí a fi wọ́n hàn nítorí pé ìjọba ti ní ètò gidi fún wọn
  9. Kí á mọ̀ pé ìjọba ti dá ilé-ẹ̀kọ́ sílẹ̀ tí a lè mú wọn lọ
  10. Kí á mọ̀ pé ibùdó ìkọ́ṣẹ́ fún àwọn àkàndá ti wà tí a lè mú wọn lọ
  11. Kí a jẹ́ kí àwọn àkàndá dara pọ̀ mọ́ akẹgbẹ́ wọn tí kì í ṣe àkàndá

Candidates’ performance was poor, general guesses were made and not as evident in the text.