Question 11
Mẹ́nu ba àwọn ọ̀rọ̀ tí bàbá Àdìó sọ nígbà tí ó para dà di wòlíì.
Observation
Candidates were expected to mention the words of Adìó’s father to the other characters when he reappeared as a prophet.
Àwọn ọ̀rọ̀ tí bàbá Àdìó sọ nígbà tí ó para da di wòlíì:
- Ó ní ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò níí jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tí ó wá bẹ̀ wọ́n wò
- Ó ní wọ́n rí wòlíì wọ́n sì ń pè é ní egúngún
- Ó ní òun sọ pé “Alelúyà” àwọn rò pé “Eríwo yà” ni òun wí
- Bàbá tún béèrè pé ǹjẹ́ Ọládẹ̀jọ kò ha ṣe ojú kòkòrò sí aya òṣìṣẹ́ rẹ̀?
- Bàbá tún béèrè pé kí ló máa ń ṣe àwọn ọmọ ènìyàn tí wọ́n máa ń pa irọ́ ojúkorojú báyìí?
- Ó ní tí Ọládẹ̀jọ bá tún purọ́, ilé rẹ̀ yóò jóná kanlẹ̀
- Ó ní ṣé ó ṣe tán tí yóò jẹ́wọ́?
- Ó ní kí ó fi ẹnu ara rẹ̀ jẹ́wọ́ kí ó sì sọ bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an
- Bàbá ní òun ń bọ̀ wá bá Àdíjá; kí Àdíjá má tíì pariwo
- Ó sọ fún Ọládẹ̀jọ pé nílé òṣìṣẹ́ rẹ̀ ni ó ti lọ bá aya òṣìṣẹ́ rẹ̀
- Ó sọ fún Àdìó pé ó yẹ gbogbo ènìyàn kó dínwó aró, kò ma yẹ atọ̀ọ̀lé
- Ó ní ṣèbí bí Ọládẹ̀jọ ṣe wáá ká aya Àdìó mọ́lé ni Àdìó náà ń mú aya Ọládẹ̀jọ lọ sílé?
- Lẹ́yìn tí ó para dà tí ó kúrò ní wòlíì, ó ní àṣírí tiwọn ló tú, ó ní ti àwọn kọ́ ló tú