Question 8
Ṣe àlàyé bí ìyàwó ọba Aṣéyìn ṣe ṣe ikú pa Irò
Observation
Candidates were required to narrate how the Queen of Aṣéyìn deceived Ìro to his death.
Bí ìyàwó ọba Asẹ́yìn ṣe ṣe ikú pa Irò:
(i) Asọ̀ àti dúkùú wọ ààrin ọba Asẹ́yìn àti olorì rẹ̀
(ii) Èyí mú kí nǹkan le díẹ̀ fún olorì; ó wáá di ẹni tí ó bẹ̀rẹ̀ sí níí ṣẹ̀gi tà.
(iii) Inú igbó ni olorì ti ṣe alábàpàdé ẹranko kan tí ó ń jẹ̀ Irò
(iv) Irò bá ayaba ní àjọṣepọ̀/eré ìfẹ́ lẹ́ẹ̀kínní
(v) Irò tún gbìyànjú láti bá ayaba ṣe eré ìfẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i nítorí pé ẹ̀ẹ̀kan tí ó ṣe kò tẹ́ ẹ lọ́rùn
(vi) Ayaba ní tí Irò yóò bá tún ṣe eré ìfẹ́ ó ní láti ṣe orò ilé bàbá òun fún òun
(vii) Irò gbà láti ṣe orò náà
(viii) Ayaba fi àáké la ìtì igi kan; kò yọ àáké
(ix) Ó ní kí Irò fi nǹkan ọmokùnrin rẹ̀ bọ inú ihò igi tí ó wà ní lílà
(x) Irò ṣe bí ayaba ṣe wí
(xi) Ayaba yọ àáké
(xii) Igi padé mọ́ nǹkan ọmọkùnrin Irò; Irò kò lè yọ nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́
(xiii) Ibẹ̀ ni Irò kú sí
Only a few candidates attempted this question. Their responses to this question portrayed failure to study the text.