Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2022

Question 5

 

Fa ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí a ṣẹ̀dá yọ nínu gbólóhùn ìsàlẹ̀ yìí kí o sì sọ ọ̀nà tí a gbà ṣẹ̀dá rẹ̀:
Bí tíṣà bá ti ń ṣe àìsùn ní àtàárọ̀ lórí ìbéèrè kíkójọ fún ìdánwò ìbẹ̀rẹ̀ sáà tuntun, bí wọ́n bá fún un ní ẹja ńláńlá, kò níí gbà á, ọ̀nà àtisùn kíákíá ni yóò ma wá.

 

Observation

Candidates were required to identify the derived words in the given sentence and explain how each word was derived.


Àfàyọ ọ̀rọ̀ tí a ṣẹ̀dá àti àlàyé ọ̀nà tí a gbà ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ náà


S/N

Àfàyọ ọrọ̀ tí a ṣẹ̀dá

Ọ̀nà tí a gbà ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ náà

a

àìsùn

A so àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àì mọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe sùn/a so àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ à àti àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ì mọ́ àpólà ìṣe sùn láti ṣẹ̀dá àìsùn

b

àtàárọ̀

A so àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti mọ́ ọ̀rọ̀-orúkọ àárọ̀/a so àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ à mọ́ àpólà atọ́kùn ti àárọ̀ láti ṣẹ̀dá àtàárọ̀

d

ìbéèrè

A so àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ì mọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe béèrè láti ṣẹ̀dá ìbéèrè

e

kíkójọ

A fi àpètúnpè ẹlẹ́bẹ ṣẹ̀dá kíkójọ lati ara àpólà ìṣe kó jọ/a fi àfòmọ́ iwájú aṣekọ́ńsónáǹtì ṣẹ̀dá kíkójọ láti ara àpólà ìṣe kó jọ

ìdánwò

a so àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ì mọ́ àpólà ìṣe dán wò láti ṣẹ̀dá ìdánwò

f

ìbẹ̀rẹ̀

a so àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ì mọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe bẹ̀rẹ̀ láti ṣẹ̀dá ìbẹ̀rẹ̀

g

tuntun

A fi àpètúnpè kíkún ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-àpèjúwe tuntun láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe tun

gb

ńláńlá

A fi àpètúnpè kíkún ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-àpèjúwe ńláńlá láti ara ọ̀rọ̀-àpèjúwe ńlá

h

àtisùn

A so àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti mọ́ ọ̀rọ̀-ìṣe sùn láti ṣẹ̀dá àtisùn/a so àfòmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ à mọ́ àpólà ìṣe ti sùn láti ṣẹ̀dá àtisùn

i

kíákíá

A fi àpètúnpè kíkún ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀-orúkọ kíákíá láti ara ọ̀rọ̀-àpọ́nlé kíá

Only a few of the candidates who tackled this question were able to give the correct explanation on how each word was derived.