Question 13
Ṣe àpèjúwe ayò títa gẹ́gẹ́ bí eré ìdárayá láàrín àwọn Yorùbá
Observation
Àpèjúwe ayò títa gẹ́gẹ́ bí eré ìdárayá kan láàrin àwọn Yorùbá
- Ọ̀kan lára àwọn eré ìdárayá ìbílẹ̀ Yorùbá ni ayò títa jẹ́
- Nígbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀ ni a máa ń ta ayò
- Tọmọdé tàgbà, tọkùnrin tobìnrin, ló ń ta ayò
- Ọpọ́n ayò àti ọmọ ayò ni ohun-èlò tí a fi ń ta ayò
- Ọpọ́n ayò ni igi tí a gbẹ́ tí ó ní ihò méjìlá; mẹ́fà mẹ́fà ní apá kọ̀ọ̀kan
- Ọmọ ayò ni èso igi tí a ṣà jọ, a tún máa ń lo kóró iṣin tàbí òkúta wẹ́wẹ́ tó ń dán
- Ọmọ ayò mẹ́rin mẹ́rin ni a máa ń kó sí ojúle kọ̀ọ̀kan nínú ọpọ́n ayò
- Ọmọ ayò méjìdínláàdọ́ta yóò pé sí inú ọpọ́n ayò kí a tóó lè bẹ̀rẹ̀ ayò títa
- Lára òfin eré ayò ni pé ènìyàn méjì péré ni ó máa ń ta ayò lẹ́ẹ̀kan náà ní ìkọjú síraa wọn
- Láti apá òsì sí apá ọ̀tún ni a máa ń ta ayò
- Ọ̀tayò kì í jẹ ayò nínú “ilé” ara rẹ̀
- Ọ̀ta ni a máa ń pe ẹni tí ó bá pa ẹni tó ń bá tayò lẹ́ẹ̀mẹta léraléra
- Ọ̀tayò tí a pa ní mẹ́ta léraléra ni Òpè
- Ọ̀tayò kò lè jẹ ju ọmọ ayò méjì tàbí mẹ́ta lọ nínú ihò kan
- Ọ̀tayò lè kún òdù
- Òdù tí kò bá jẹ ni a máa ń sọ pé “ó fò tàbí ó jù”
- Ọ̀tayò tí ó bá jẹ ọmọ ayò tí ó lé ní mẹ́rìnlélógún ni ó pa
- Tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọ̀tayò méjèèjì bá jẹ mẹ́rìnlélógún, ọ̀mì ni wọ́n ta yẹn
- “Mo kí ọ̀ta, mo kí òpè” ni a máa ń kí àwọn ọ̀tayò
- Ìdáhùn ìkíni yìí ni “Ọ̀ta ń jẹ́, òpè ni kò gbọdọ̀ fọhùn”
- Wọn kì í sábà jà ní ìdí eré ayò nítorí pé “Eré ni à ń fi ọmọ ayò ṣe”
- Àǹfààní láti ṣe àwàdà àti láti sọ ọ̀rọ̀ apanilẹ́rìn-ín wà fún àwọn ọ̀tayò àti èrò ìwòran
- Ayò títa máa ń kọ́ni lọ́gbọ́n
- máa ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan níbi ayò títa Òjóóró
Candidates who attempted this question tackled it well.