Question 12
Ṣe àpèjúwe ojúṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn wọ̀nyí nínú ètò agbo-ilé
Observation
Candidates were required to explain the roles of the family head, the oldest wife and the male children in Yoruba traditional family setting.
(a) Ojúṣe Baálé:
i. píparí ìjà láàrín àwọn ọmọ-ilé
ii. àlejò gbígbà sí agbo-ilé
iii. lílé àlejò búburú kúrò nínú agbo-ilé
iv. ṣíṣe àbójútó ìfiọmọlọ́kọ/ìfẹ́bìnrinfọ́mọ
v. ṣíṣe ìtọ́jú aboyún ilé
vi. ṣíṣe ètò ìsọmọlórúkọ/ìkómọjáde
vii. gbígba owó-orí àwọn ọmọkùnrin ilé jọ
viii. mímójútó orò ilé
ix. mímójútó ètò ìsìnkú
x. ṣíṣe agbẹnusọ fún agbo-ilé nínú ìpàdé ìlú/àdúgbò
xi. mímójútó ètò oyè jíjẹ tí ó kan agbo-ilé
(b) Ojúṣe Ìyáalé:
i. bíbá baálé ilé dámọ̀ràn
ii. ṣíṣe àlàyé ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ọjọ́-orí àwọn ọmọ ilé
iii. ṣíṣe àkóso àwọn obìnrin-ilé/ìyàwó-ilé
iv. ṣíṣe ìtọ́jú ìyàwó tuntun
v. ṣíṣe àkóso àwọn obìnrin níbi ayẹyẹ/ìnáwó/ọdún/orò ilé
vi. ṣíṣe ìtọ́jú aboyún àti ọmọ wẹ́wẹ́ ní agbo-ilé
vii. píparí ìjà láàrin àwọn obìnrin-ilé/ìyàwó-ilé
viii. píparí ìjà láàrin àwọn ọmọ-ilé lóbìnrin
ix. mímójútó ìmọ́tótó agbo-ilé
x. ṣíṣe ètò ìgbàlejò ní agbo-ilé
(d) Ojúṣe Ọmọkùnrin-ilé:
i. ríran àwọn àgbà ilé lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó gba agbára bíi igi lílà, títún ilé kọ́, abbl
ii. ríro àyíka agbo-ilé
iii. ṣíṣe aṣojú agbo-ilé nínú iṣẹ́ ogun jíjà
iv. pípa koríko bẹẹrẹ/ewé/imọ̀ fún ìlò ilé tàbí ìlú
v. gbígbẹ́ ilẹ̀ láti sin ibi ọmo, òkú àbíkú, abbl
vi. pípa ẹran níbi ìnáwó agbo-ilé
vii. ríran àwọn àgbà ilé lọ́wọ́ níbi àṣeyẹ/ìnáwó agbo-ilé
viii. ṣíṣe aṣojú agbo-ilé nínú iṣẹ́ ìlú bíi ọ̀nà yíyẹ̀, odò gbígbẹ́, ìdáàbòbò ìlú, títún ààfin kọ́, abbl
ix. kíkópa nínú ọ̀wẹ̀ tí ó pa ọmọ-ilé pọ̀
Most of the candidates who attempted this question performed fairly well.