Yoruba Paper 2 WASSCE (SC), 2022

Question 9

 

Sọ̀rọ̀ lórí àṣà fífi obìnrin sínú ìgbèkùn tí Mọrèmi lòdì sí.

Observation

Candidates were expected to explain the various means of by which women were subjected to captivity that Mọrèmi frowned at in the prose.

  1. Fífá orí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú dán/kodoro
  2. Mímú obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú wọ aṣọ dúdú fún odindi ọdún kan láti fi ṣọ̀fọ̀ ọkọ rẹ̀
  3. Kí wọ́n má jẹ́ kí ìyàwó òkú wẹ̀, kí ó má ṣoge fún ọdún kan
  4. Kí wọ́n sọ ìyàwó òkú sí àtìmọ́lé láìjáde, kí ó fi lè wà ní ilé opó
  5. Fífún àwọn ìyàwó òkú ní omi tí wọ́n fi wẹ òkú mu láti fi lè mọ ẹni tí ó pa ọkọ wọn nínú wọn
  6. Fífi ipá ṣú ìyàwó òkú lópó fún ìbátan òkú láìti ọkàn ìyàwó òkú wá
  7. Mímú kí obìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ máa jẹ ọbẹ̀ àtẹ́ fún ọjọ́ méje lẹ́yìn ìbímọ
  8. Kí wọ́n máa fi ọmọbìnrin fọ́kọ láti pínníṣín  
  9. Bí wọ́n ṣe fún Ọ̀gbẹ̀rgún ni aáyan jẹ́ fún ọjọ́ méje lẹ́yìn tí ó bímọ  
  10. Bí wọ́n ṣe dábẹ́ fún ìyá Ọ̀gbẹ̀gún nígbà tí ó wà nípò ìlóyún nítorí pé wọ́n gbàgbọ́  pé ọmọ kò gbọ́dọ̀ forí kan nǹkan kan lójú ara aláboyún tó fẹ́ bímọ
  11. Bí olóyè Omíyalé ṣe fìyà jẹ Mosún tí ó sì sọ ọ́ di olóòórùn àti aláìsàn nítorí pé bàbá Mosún fi í ṣọfà lọ́dọ̀ rẹ̀
  12. Kí gbogbo obìnrin bẹ̀rẹ̀ síí san ẹgbàajì owó ẹyọ gẹ́gẹ́ bí owó-orí

 

Candidates’ performance in this question was poor, it shows that Candidates had shallow knowledge of the set text.