Question 10
Nínú ewì : “Ajá”, dárúkọ mẹ́wàá nínú àwọn àwòmọ́ tí akéwì sọ pé Ajá ní
Candidates were required to mention ten characteristic features of dog as evident in the poem.
Àwọn àwòmọ́ tí akéwì sọ pé ajá ní:
- Àtẹran àtegungun ni ajá máa ń jẹ
- Ó fẹ́ràn láti máa fi gbígbó rẹ̀ já ènìyàn láyà
- Ó ní ọ̀gàn tó fara jọ ọkọ́ àgbẹ̀
- Ó tún máa ń kùn láti dẹ́rù ba ènìyàn
- Ojú rẹ̀ á máa ríran gan-an: ní pàtàkì, àwọn ohun tí ojú ènìyàn lásán ò lè rí
- Gbogbo ìgbà ni imú rẹ̀ máa ń tutù/rin
- A máa gbọ́ òórùn gan-an
- Ẹranko tó lè sáré dáadáa ni
- Ó ní èékánná ṣọ̀bọ̀lọ̀ ṣọ̀bọ̀lọ̀ tí ó fi máa ń tú ìfun ẹran tí ó bá pa
- Ẹranko tí ó máa ń ṣọdẹ ni láyè ara rẹ̀
- A lè lò ó láti fi mú ọ̀daràn/olè
- A máa jí ẹran ẹlẹ́ràn jẹ nígbó
- Ó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tàbí ọ̀tá fún ènìyàn/ẹranko
- Tó bá ti ya dìgbolugi, kò tún mọ ojú ẹnikẹ́ni mọ́
- A máa pe àkíyèsí olówó ẹ̀ sí nǹkan abàmì tó bá rí
- À ń lò ó làti pèsè ààbò/fi ṣọ́ ilé
- Ó tún máa ń ran ọdẹ tí ó jẹ́ olówó rẹ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ọdẹ
- Ó máa ń sọ olówó rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípa pípa ẹran lọ́pọ̀lọpọ̀ tí olówó rẹ̀ lè tà
Candidates’ performance was poor, general guesses which were outside the poem were made.