Question 8
Irú ènìyàn wo ni Adigé jẹ́
Candidates were expected to describe the features of the oral literature chanter as evident in the text.
Irú ènìyàn tí adígè jẹ́:
(i) Ẹnikẹ́ni ni ó lé dígè, ìbáà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ọmọdé tàbí àgbàlagbà
(ii) Adígè gbọ́dọ̀ ní ẹ̀bùn ègè dídá
(iii) Adígè gbọ́dọ̀ ní ẹ̀bùn ohùn dídùn
(iv) Adígè lè wọ irú aṣọ tí ó bá wù ú lójú agbo
(v) Adígè gbọ́dọ̀ lè ṣe àkíyèsí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àwùjọ
(vi) Àdígè ní láti jẹ́ aláròjinlẹ̀
(vii) Adígè gbọ́dọ̀ jẹ́ awíko-n̄-ko-lójú-ọlọ́rọ̀
(viii) Adígè gbọ́dọ̀ gbọ́n nínú, gbọ́n lẹ́yìn
- Adígè gbọ́dọ̀ mọ bí a ṣe ń fi èdè dárà; kí ó tún ṣe àgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò fi mú ni lọ́kàn
- Adígè gbọ́dọ̀ mọ bí a ṣe ń dápàárá/ṣàwàdà
- Ó gbọ́dọ̀ mọ ènìyàn í kì tí orí ẹni tí wọ́n ń kì yóò fi wú tí yóò sì ná owó fún adígè
- Ó gbọ́dọ̀ mọ bí a ṣe ń fi àdúrà/ìwúre kọ̀ọ̀kan há ègè dídá rẹ̀
- Ó gbọ́dọ̀ mọ ọpẹ́ í dá fún àwọn tí ó bá ṣe é lóore.
Only a few candidates attempted this question. Their responses to this question portrayed failure to study the text.