Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2023

Question 12

 Ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bí a ṣe ń ṣe àkàrà

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bí a ṣe ń ṣe àkàrà:

  1. Erèé/ẹ̀wà ni a fi ń ṣe àkàrà
  2. A ó rẹ ẹ̀wà/erèé sínú omi kí èèpo ẹ̀yìn rẹ̀ lè rọ̀
  3. A lè fi ọwọ́ bó èèpo yìí tàbí kí a fi ẹsẹ̀/odó bó o
  4. A ó ṣan gbogbo èèpo yìí kúrò lára erèé/ẹ̀wà, a ó sì lọ̀ ọ́
  5. A lè lọ̀ ọ́ papọ̀ mọ́ àlùbọ̀sà àti ata tàbí kí a wẹ́ àlùbọ́sà àti ata yìí sọ́tọ̀ tí a ó máa pò ó mọ́ ọn tí a bá fẹ́ dín in
  6. Omi kò gbọdọ̀ pọ̀ jù nínú rẹ̀ tí a bá ń lọ̀ ọ́/pò ó nítorí pé kò gbọdọ̀ ṣàn
  7. A ó fi ọmọ-orógùn rò ó dáadáa kí ó bà lè fẹ́lẹ́ lẹ́yìn tí a ti fi iyọ̀ àti àwọn èròjà mìíràn tí a bá fẹ́ sí i
  8. A ó gbe agbada/apẹ tí a fẹ́ fi dín in lé orí iná
  9. A ó da epo/òróró tí a fẹ́ fi dín in sínú agbada/apẹ; a ó jẹ́ kí ó gbá dáadáa
  10. A ó bẹ̀rẹ̀ sí níí fi ọwọ́/ṣíbí dá erèé/ẹ̀wà pípò sínú epo/òróró tí ó ti gbá
  11. Bí a bá ṣe fẹ́ kí ó tóbi tó ni a ó ṣe dá a
  12. A ó máa fi igi/ṣíbí/ìwàkàrà yí i padà lórí iná títí tí yóò fi jiná
  13. Bí ó bá ti jiná dáadáa, a ó wà á sínú asẹ́
  14. Lẹ́yìn èyí, àkàrà di jíjẹ tàbí títà

                         

Only a few of the candidates who attempted this question grasped the requirement of the question.