Question 11
Irú ènìyàn wo ni Oyèládùn jẹ́?
Candidates were required to describe Oyeladun’s person as evident in the text.
Irú ènìyàn tí Oyèládùn jẹ́:
- Àdìó ni orúkọ bàbá Oyèládùn
- Àbẹ̀ní ni orúkọ ìyá rẹ̀
- Kò bá ọlá kankan ní ilé rárá/Kòlàkòṣagbe ni àwọn òbí rẹ̀
- Kíláàsì kẹta ló wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama tí kò fi sí owó lọ́wọ́ bàbá rẹ̀ láti rán an lọ
sílé-ẹ̀kọ́ mọ́; nítorí bíbọ́ tí iṣé bọ́ lọ́wọ́ bàbá rẹ̀
- Àwọn obí rẹ̀ fi í ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ lọ́dọ̀ Àlàájà Àdíjá, ìyàwó Ọládẹ̀jọ
- Ó gbọ́ èkọ́-ilé, ó sì mọ iṣẹ́-iléé ṣe
- Kì í ṣe ọ̀lẹ; òun ló kọ́kọ́ máa ń jí láti ṣe iṣẹ́-ilé kí ẹnikẹ́ni tóó jí ní ilé ọ̀gá rẹ̀
- Ó ní ọpọlọ pípé; òun ló ń bá Bọ́sípò, ọmọ ọ́gá rẹ̀, ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀
- Kì í ṣe oníṣekúṣe ọmọ; ó gbá Bọ̀sípò létí nígbà tí ìyẹn gbá a nídìí
- Ọmọ tó gbọ́n ni; ó kọ̀ láti bá Bọ̀sípò ṣe ọ̀rẹ́ nítorí pé ó gbà pé Bọ̀sípò gọ̀
- Kì í ṣe onínàákúnàá ọmọ; ọwọ́ ìyá rẹ̀ ní ó máa ń kó owó tí Bọ́sípò bá fún un pamọ́ sí
- Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí rẹ̀; ó sáré lọ sọ fún àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí ó gbọ́ pé Ọládẹ̀jọ fẹ́ẹ́ dá bàbá rẹ̀ dúró lẹ́nu iṣẹ́
- Ó jẹ́ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́-ìwé
- Òun nìkan ṣoṣo ni àwọn òbí rẹ̀ bí
- Ó máa ń ran àwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́; ó ń bá ìyá rẹ̀ kiri ọjà
Candidates who attempted the question performed fairly well.