Question 13
Àwọn ẹ̀kọ́ two ni àwọn ọmọ-ọdẹ máa ń kọ́ níbi ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọdẹ?
Candidates were required to state all the lessons that hunters usually acquire while on training.
- Yóò kọ́ nípa lílo onírúurú irinṣẹ́ ọdẹ
- Yóò kọ́ bí a ti ń fi ojú sun ẹran tí ìbọn, ọfà tàbí àkàtàǹpó kò fi níí tàsée rẹ̀
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń gẹ̀gùn àti bí a ṣe ń lúgọ de ẹranko tí a fẹ́ẹ́ pa
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń mọ̀ pé ẹranko ń bọ̀ láti apá ibì kan
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń rìn nínú igbó tí a kò fi níí lé ẹran lọ
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń yin ìbọn tí kò níí ba ọdẹ mìíràn tí wọn jọ lọ sí ìgbẹ́
- Yóò kọ́ nípa ọ̀gangan ibi tí a máa ń yin ìbọn sí ní ara ẹran tí yóò fi lè pa á ní àpafọ̀n tí ẹran náà kò fi níí gbé ọgbẹ́ ìbọn sá lọ/fi ẹ̀tù ṣòfò
- Yóò kọ́ bí ọdẹ ṣe ní láti máa sọ̀rọ̀ nínú igbó; kí ẹranko má bàá gbọ́ ohùn ọdẹ kí ó sì sá lọ
- Ó ní láti kọ́ nípa ètùtù ṣíṣe fún ẹranko abàmì tí ó bá pa
- Yóò kọ́ nípa àwọn èèwọ̀ ọdẹ
- Ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọdẹ gbọ́dọ̀ kọ́ ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni, ìgboyà, ìlawọ́, ìforítì, sùúrù àti ìjáfáfá
- Yóò kọ́ nípa oríṣiríṣi oògùn tí ọdẹ fi ń ṣe agbára
- Yóò kọ́ nípa àwọn igbó àìwọ̀ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbà ọdẹ
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń bọ Ògún
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń ní ìfura
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń lo ajá láti dẹ ìgbẹ́
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń dẹ pàkúté/pańpẹ́/gbóró, ìrín, ọṣọ́, ìgèrè, abbl
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń kun ẹran tí a bá pa
- Yóò kọ́ bí a ṣe ń yan ẹran tí a pa
Some of the candidates who attempted this question did justice to it.