Yoruba Paper 2 WASSCE (PC), 2023

Question 9

Ṣàlàyé ohun tí ó ṣe okùnfà ikú Adéṣẹwà.

Candidates were required to explain what led to the death of Adesewa, one of the characters in the prose text.

Ohun tí ó ṣokùnfà ikú Adéṣẹwà:

  1. Obìnrin kan wà tí ó ń jẹ́ Ọmọ́tórera
  2. Ó bí ọmọkùnrin kan ṣoṣo
  3. Ọmọ náà tó ọmọ ọdún mẹ́rìnlá
  4. Ọmọ náà kò tíì bàlágà tán tí ìyá rẹ̀, Tórera, fi wá àfẹ́sọ́nà fún un
  5. Adéṣewà ni orúkọ àfẹ́sọ́nà náà
  6. Tórera ru nǹkan ìdána lọ fún àwọn òbí Adéṣẹwà
  7. Kò pẹ́ púpọ̀ ni ọmọ Tórera fò ṣánlẹ̀, tó kú
  8. Lẹ́yìn oṣù mélòó kan tí ọmọ Tórera kú ni Tórera gbé Adéṣẹwà ní ìyàwó
  9. Tórera lọ pe ọkùnrin kan wá láti wá bá Adéṣẹwà ní àṣepọ̀
  10. Ó rò pé Àdéṣẹwà yóò lè lóyún fún òun
  11. Ọkùnrin tí Tórera tún pé jẹ́ oníkọ́ọfée
  12. Ọkùnrin náà kò lágbára láti ṣe ohun kankan pẹ̀lú Adéṣẹwà lálẹ́ ọjọ́ náà, ó sì bá tirẹ̀ lọ
  13. Tórera kò dẹ̀yìn lẹ́yìn ọ̀ràn yìí
  14. Ó tún lọ pe oníjàgídí-jàgan ẹ̀dá kan láti wá kọlù Ṣẹwà
  15. Ìyẹn mú géńdé mẹ́ta kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí Tórera gbé fún un
  16. Wọ́n fi ipá bá Ṣẹwà lò pọ̀
  17. Bí Ṣẹwà ṣe ráyè jàjà bọ́ lóru ọjọ́ yìí, igbó ló torí bọ̀, tí ó sì sá jáde nílùú
  18. Ọjọ́ kẹta ni wọ́n rí òkú Ṣẹwà

 

Candidates’ performance in this question was poor.